Top Songs By King Dr. Saheed Osupa
Similar Songs
Credits
PERFORMING ARTISTS
King Dr. Saheed Osupa
Performer
Okunola Saheed
Drums
COMPOSITION & LYRICS
Okunola Saheed
Songwriter
PRODUCTION & ENGINEERING
Okunola Saheed
Producer
Lyrics
Saheed Òṣùpá o
Ọba orin mà tún dé o
Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán
(Saheed Òṣùpá o)
(Ọba orin mà tún dé o)
(Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán)
Saheed Òṣùpá o
Ọba orin mà tún dé o
Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán
(Saheed Òṣùpá o)
(Ọba orin mà tún dé o)
(Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán)
Òṣùpá yọ lókè gbogbo ìràwọ̀ o, ma wólẹ̀ kíá o
Ọba ìràwọ̀, ògo ló wọlé dé
(Saheed Òṣùpá o)
(Ọba orin mà tún dé o)
(Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán)
Òṣùpá yọ lókè gbogbo ìràwọ̀ o, ma wólẹ̀ kíá o
P’Ọba ìràwọ̀, ògo ló wọlé dé
(Saheed Òṣùpá o)
(Ọba orin mà tún dé o)
(Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán)
Ìlá sí ìlalà, ẹ tètè mọ̀ o wí pé ó jìn réré o
Kìí ṣe ibì kan ta le sáré lọ wéré
(Saheed Òṣùpá o)
(Ọba orin mà tún dé o)
(Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán)
Ìlá sí ìlalà, ẹ tètè mọ̀ o wí pé ó jìn réré o
Kìí ṣe ibì kan ta le sáré lọ wéré
(Saheed Òṣùpá o)
(Ọba orin mà tún dé o)
(Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán)
Ọgbọ́n pẹ̀lú agọ̀ ìyàtọ̀ ààrin wọn pọ̀ gan ni
Ká má ì s’òye t’ọ́lọ́gbọ́n wárí fún
(Saheed Òṣùpá o)
Ọba orin mà tún dé o)
(Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán)
Ọgbọ́n pẹ̀lú agọ̀ ìyàtọ̀ ààrin wọn pọ̀ gan ni
Ká má ì s’òye t’ọ́lọ́gbọ́n wárí fún
(Saheed Òṣùpá o)
Ọba orin mà tún dé o)
(Èmi lapèdé bí ẹni láyin mọ́n’rán)
Ìbà Kábíèsí ( Olúwa Ọba)
Kábíèsí o (Olúwa Ọba)
Paríparíọlá (Olúwa Ọba)
Paríparíọlá (Olúwa Ọba)
Ọba Adàgbàmátẹ̀pá (Olúwa Ọba)
Adàgbàmátẹ̀pá o (Olúwa Ọba)
Arúgbó ọjọ́ (Olúwa Ọba)
Ọba Arúgbó ọjọ́ (Olúwa Ọba)
Àríìrọ́àlá o (Olúwa Ọba)
Ọba Àríìrọ́àlá (Olúwa Ọba)
Ìbà àwọn tó láyé (Mo júbà ayé tótó)
Àwọn tó layé (Mo júbà ayé tótó)
Àwọn ìyá mi (Mo júbà ayé tótó)
Hmmn (Mo júbà ayé tótó)
Afẹ́gẹgẹníyẹ̀ẹ́ (Mo júbà ayé tótó)
Hmmn (Mo júbà ayé tótó)
Òjìjífirì (Mo júbà ayé tótó)
Ah (Mo júbà ayé tótó)
(Mo júbà ayé tótó)
Eléjìgboòròrò (Mo júbà ayé tótó)
Ahh (Mo júbà ayé tótó)
Ẹ̀ ń gbóhùn mi (orin j’orin lọ)
Ṣèbí ẹ̀ ń gbóhùn mi o (orin j’orin lọ)
Àdìtú èdè (orin j’orin lọ)
Hmmn (orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
Hmmn (Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
(Orin j’orin lọ)
Láti ibi lọ sí Ìbàdàn lọ dé Sokoto
Gbogbo African countries dé ìlú Ọba
Wọ́n ń sọ pé Fújì Music Sedo ni wọ́n fẹ́ jó
(Láti ibi lọ sí Ìbàdàn lọ dé Sokoto)
(Gbogbo African countries dé ìlú Ọba)
(Wọ́n ń sọ pé Fújì Music Sedo ni wọ́n fẹ́ jó)
Láti ibi lọ sí Ìbàdàn lọ dé Sokoto o
Gbogbo African countries dé ìlú Ọba
Wọ́n ń sọ pé Fújì Music Sedo ni wọ́n fẹ́ jó
(Láti ibi lọ sí Ìbàdàn lọ dé Sokoto)
(Gbogbo African countries dé ìlú Ọba)
(Wọ́n ń sọ pé Fújì Music Sedo ni wọ́n fẹ́ jó)
Ìrèké máa mújó whatsup yìí ma mújó
Arabo ma mújó t’álùjó ò bá ti dúró
Láti ibi lọ sí Ìbàdàn lọ dé Sokoto
Gbogbo African countries dé ìlú Ọba
Wọ́n ń sọ pé Fújì Music Sedo ni wọ́n fẹ́ jó
(Láti ibi lọ sí Ìbàdàn lọ dé Sokoto)
(Gbogbo African countries dé ìlú Ọba)
(Wọ́n ń sọ pé Fújì Music Sedo ni wọ́n fẹ́ jó)
Ẹ̀yin gan ò ní lè ṣé
Tẹ dẹ̀ gb’álùjó
Ẹ wá ní ẹ ò ní sọ ìdí
Ó tún yá ẹ gbéra ẹ bá mi sọ̀kọ́ ijó láti ibí lọ sí Ìbàdàn lọ dé Sókótó o
Gbogbo African Countries dé ìlú Ọba
Wọ́n ń sọ pé Fújì Music Sedo ni wọ́n fẹ́ jó
(Láti ibi lọ sí Ìbàdàn lọ dé Sokoto)
(Gbogbo African countries dé ìlú Ọba)
(Wọ́n ń sọ pé Fújì Music Sedo ni wọ́n fẹ́ jó)
Ó ti gbìyànjú gan ni (k’orin tó d’ọbẹ̀)
Ó ti gbìyànjú gan ni (k’orin tó d’ọbẹ̀)
Ni wọ́n ṣe dìbò fún Ọba orin (p’óhun ló J’Ọba orin kárí)
Ni wọ́n ṣe dìbò fún Ọba orin (p’óhun ló J’Ọba orin kárí)
Ó kọ Jùjú gidi (ló fi wá J’Ọba orin kárí)
Àpàlà ẹ̀ gbẹnután (ló fi wá J’Ọba orin kárí)
Pop ẹ̀ Super (ló fi wá J’Ọba orin kárí)
Highlife ò dẹrùn (ló fi wá J’Ọba orin kárí)
Ó ti lùlù fún Ọba gan (Ó lù fún ìjòyè)
Ó ti lùlù fún Ọba gan (Ó lù fún ìjòyè)
Ó ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ níbi (Ká f’ijó rin ìrìn àjò kiri)
Ó ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ níbi (Ká f’ijó rin ìrìn àjò kiri)
Doctor of Music (Ká f’ijó rin ìrìn àjò kiri)
King of Lyrics (Ká f’ijó rin ìrìn àjò kiri)
Fújì Maestro (Ká f’ijó rin ìrìn àjò kiri)
Cultural Ambassador (Ká f’ijó rin ìrìn àjò kiri)
Ahh (Ká f’ijó rin ìrìn àjò kiri)
Lágbájá mà lè kọrin
Làkáṣègbè ń kọrin
Bó jẹ́ ti ká pèdè àsìkò ṣèbí àwa ló lorin
(Lágbájá mà lè kọrin)
(Làkáṣègbè ń kọrin)
(Bó jẹ́ ti ká pèdè àsìkò ṣèbí àwa ló lorin)
Lágbájá mà lè kọrin o
Làkáṣègbè ń kọrin
Bó jẹ́ ti ká pèdè àsìkò ṣèbí àwa ló lorin
Làkáṣègbè ń kọrin)
(Bó jẹ́ ti ká pèdè àsìkò ṣèbí àwa ló lorin)
B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi
B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi)
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni)
Saheed wọ́n mọ̀ pé o
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi)
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni)
Kòsí tàbí sùgbọ́n o
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi)
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni)
Àwa ló leré o
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi)
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni)
17, 18, 19 baby
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi)
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni)
Ọmọdé ni ẹ́ o tí ń rèdí
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi)
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni)
Kí ló wá ṣe ẹ́ to wá ń wò mí
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi)
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni)
Ṣo fọ́ fún mi kọ́ lo fi ń wò mí
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi)
(B’éré bá jẹ́ eré ìjìnlẹ̀ gidi ni)
Bí wọ́n ṣe ró dẹ́dẹ́, ni wọ́n ṣe kàn dudu
Mo níbo ló dà wọ́n lágbo
(Saridon P àwa ò lè gbórin aládùn ká má jo Saridon P)
Òṣùpá ń kọrin ọgbọ́n, ó ń làlùjó
Ó ń dá’ṣà, ó lẹ́fẹ̀ lọ́wọ́ gan
(Gbogbo eré l’Òṣùpá Saheed yẹn má ń ṣe gbogbo eré)
À ló ń kọrin ọgbọ́n, ó ń làlùjó
Ó ń dá’ṣà, ó lẹ́fẹ̀ lọ́wọ́ gan
(Gbogbo eré l’Òṣùpá Saheed yẹn má ń ṣe gbogbo eré)
Orin wá miringindin ó miringindin
Tùngbá Fújì mi tún le
(Gbogbo ijó làwọn tán mọ Fújì mi fí ń jo)
Àl’órin wá miringindin ó miringindin
Tùngbá Fújì mi tún le
(Gbogbo ijó làwọn tán mọ Fújì mi fí ń jo)
Premiership ni wọ́n fi ń díje ní England ni
(La liga wọ́n fi ń díje ń díje Spain)
(Serie-a wọ́n fi ń díje ní Italy ni)
(Bundesliga wọ́n fi ń díje Germany)
(Ligue-1 wọ́n fi ń díje France ni)
(Tí wọ́n bá gba tán wọ́n á kó qualifiers jọ)
(Àwọn Qualifiers ni wọ́n máa díje Champion yẹn)
(Tí Champion bá ti wá na Champions pa)
(Real Madrid ṣe ba ojú Borrusia jẹ́)
(Ọ̀gá àgbà ni wọ́n má wá padà gbé’fe fún)
Bó ṣe ń lọ mà ṣá nìyẹn lórí pàpá ìṣeré
Premiership ni wọ́n fi ń díje ní England ni
(La liga wọ́n fi ń díje ń díje Spain)
(Serie-a wọ́n fi ń díje ní Italy ni)
(Bundesliga wọ́n fi ń díje Germany)
(Ligue-1 wọ́n fi ń díje France ni)
(Tí wọ́n bá gba tán wọ́n á kó qualifiers jọ)
(Àwọn Qualifiers ni wọ́n máa díje Champion yẹn)
(Tí Champion bá ti wá na Champions pa)
(Real Madrid ṣe ba ojú Borrusia jẹ́)
(Ọ̀gá àgbà ni wọ́n ma wá padà gbé’fe fún)
Saridon Papa nínú Olórin Champion ni
(Lyrically, ó ṣiṣẹ́ di star ni)
(Lati star ó ṣiṣẹ́ di super ni)
(Láti Super ó díje wọ mega ni)
(Megally, ó ti wá di àlùjọ̀nú)
(Legendary, ó ti wá padà d’ẹbọra)
Ẹ ẹ̀ m’Òṣùpá Saheed ni?
Ọba orin tó jóná bi Mercy
(Ó ta bi Ronaldo)
(Ó súnmọ Grammy)
(Ó jóná ju Korra lọ)
(Rosiski nínú olórin o ò lè le bá o)
(Lampadi nínú olórin ìyẹn ń bẹ ni)
Ẹ ẹ̀ m’Òṣùpá Saheed ni?
Ọba orin Saheed ò m’eré
Ọba orin tó jóná bi Mercy
(Ó ta bi Ronaldo)
(Ó súnmọ Grammy)
(Ó jóná ju Korra lọ)
(Rosiski nínú olórin o ò lè le bá o)
(Lampadi nínú olórin ìyẹn ń bẹ ni)
T’ọn bá sọ pé wọ́n mọ̀ s’ára
(Á jẹ́ pé ó ti bà wọ́n rí)
(Èèyàn tí ò jagun kò lè mọ gravity ogun)
(Ọ̀ràn t’Ágẹmọ dá o, ó ń bẹ lọ́rùn ògúndìji)
(Bó ṣe ń ṣe Gbọ́tìjà láyé o Gbógunmì ni ẹ lọ bi)
Òṣùpá ẹnií bà ló mà mọ̀ o
Tí wọ́n bá sọ wí pé wọ́n mọ̀ s’ára
(Á jẹ́ pé ó ti bà wọ́n rí)
(Èèyàn tí ò jagun kò lè mọ gravity ogun)
(Ọ̀ràn t’Ágẹmọ dá o, ó ń bẹ lọ́rùn ògúndìji)
(Bó ṣe ń ṣe Gbọ́tìjà láyé o Gbógunmì ni ẹ lọ bi)
T’ọn bá sọ wí pé búrẹ́dì wà o
(Ẹ̀wá wà o, á jẹ́ p’ówó wà, wèré tún wà o)
(Kó tó di pé Ọlọ́hun Butter bread wa)
(La ti ní wèrè ńlẹ̀ tó ti pọ̀ rẹpẹtẹ)
Àṣà t’ọ́n dá nísẹ̀nyí nìyẹn
T’ọn bá sọ wí pé búrẹ́dì wà o
(Ẹ̀wá wà o, á jẹ́ p’ówó wà, wèré tún wà o)
(Kó tó di pé Ọlọ́hun Butter bread wa)
(La ti ní wèrè ńlẹ̀ tó ti pọ̀ rẹpẹtẹ)
Torí ẹni bá ti lówó ní láti ní wèrè
(Ó kàn lè jẹ́ wèrè pẹ̀lú integrity ni)
(T’éèyàn ò bá ní wèrè rárá wọ́n á kàn máa rẹjẹ)
(Kó tó di pé Ọlọ́hun butter bread wa)
(La ti ní wèrè ńlẹ̀ tó ti pọ̀ rẹpẹtẹ)
Bó ṣe wà nílé ayé nìyẹn
Ṣẹ rí ẹni bá ti lówó ní láti ní wèrè
(Ó kàn lè jẹ́ wèrè pẹ̀lú integrity ni)
(T’éèyàn ò bá ní wèrè rárá wọ́n á kàn máa rẹjẹ)
(Kó tó di pé Ọlọ́hun butter bread wa)
(La ti ní wèrè ńlẹ̀ tó ti pọ̀ rẹpẹtẹ)
Bó ṣe wà nílé ayé nìyẹn
Ko tó d’alayé wa ti ní connections gan
(Ko tó di gíràn-án wa ní choco tó pọ̀ gan)
(Ko tó di bàbá ọjà lọ́nà customer ti pọ̀ gan)
Ko tó d’alayé ọ̀rẹ́ mi, wà ti mọ èèyàn gan
(Ko tó d’alayé wa ti ní connections gan)
(Ko tó di gíràn-án wa ní choco tó pọ̀ gan)
(Ko tó di bàbá ọjà lọ́nà customer ti pọ̀ gan)
To bá pọ́n mi lé, ma pọ́n ẹ lé
(Souvenir ò kí ń ṣe ọ̀fẹ́ o)
(Ẹni tó wọ aṣọ ni wọ́n ma fún)
(Mr kò ra Àǹkárá má lọ béèrè Semo)
(Èèyàn Tó ṣe normal ní party mi lèmi á tọ́jú)
Kò sáyè mo gbọ́ mo branch o
To bá pọ́n mi lé, ma pọ́n ẹ lé
(Souvenir ò kí ń ṣe ọ̀fẹ́ o)
(Ẹni tó wọ aṣọ ni wọ́n ma fún)
(Mr kò ra Àǹkárá má lọ béèrè Semo)
(Èèyàn Tó ṣe normal ní party mi lèmi á tọ́jú)
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní èkó o?
Ẹ gbọ́ kí ló ń ṣẹlẹ̀ lékòó ta ni alága báyìí?
(Ẹ tan ná ká ríran, wọ́n ní lábẹ́ bó ṣe wù kó ṣe rí ọ)
(Mustapha Adekunle mi Sego ni)
(Tó bá w’ọ̀sán kó tún tí padà kó d’òru)
(Èkó ń lọ pé SEGO nation la bá lọ)
(Inu wọn ń dùn pé Sego nation l’alága)
Àní kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní èkó o?
Ẹ gbọ́ kí ló ń ṣẹlẹ̀ lékòó ta ni alága báyìí?
(Ẹ tan ná ká ríran, wọ́n ní lábẹ́ bó ṣe wù kó ṣe rí ọ)
(Mustapha Adekunle mi Sego ni)
(Tó bá w’ọ̀sán kó tún tí padà kó d’òru)
(Èkó ń lọ pé SEGO nation la bá lọ)
(Inu wọn ń dùn pé Sego nation l’alága)
Bàbá èbúté ẹ gbà fun ọmọ Hindu ni
(Baby Nàìjíríà ọmọ Aṣíwájú là ń sọ)
(Èèyàn Ṣèyí ọmọ Tinúubú mà ni)
(Tó bá w’ọ̀sán kó tún tí padà kó d’òru)
(Èkó ń lọ pé SEGO nation la bá lọ)
(Inu wọn ń dùn pé Sego nation l’alága)
MC Musiliu mi, MC Musiliu padà di bàbá
(Ẹnu j’ẹnu lọ)
(Pẹ̀lú atótónu gbogbo pé ó ṣe’gbá ṣ’àwo)
(Irú wá ògiri wá padà wá gbà fun)
(Ẹ̀dá ò dà bí Ọlọ́hun ko wa tán bí o)
(Gbogbo National ni wọ́n gbà wí pé Ààrẹ wọn ni)
MC Musiliu mi, MC Musiliu padà di bàbá
(Ẹnu j’ẹnu lọ)
(Pẹ̀lú atótónu gbogbo pé ó ṣe’gbá ṣ’àwo)
(Irú wá ògiri wá padà wá gbà fun)
(Ẹ̀dá ò dà bí Ọlọ́hun ko wa tán bí o)
(Gbogbo National ni wọ́n gbà wí pé Ààrẹ wọn ni)
Ẹni ò dùn mọ́ whatever kó pẹjọ́
(Musiliu máa ṣe dáadáa lọ ní tì ẹ)
(Sọ pé Ọlọ́hun ló ni ẹ́, o ò lè wálẹ̀ mọ́)
(To bá bẹ̀rẹ̀ o fẹ́ wọ helicopter ni)
(Ẹ̀dá ò dàbí Ọlọ́hun kò wá tán bí o)
(Gbogbo National ni wọ́n gbà wí pé Ààrẹ wọn ni)
Olùgbàyè tí ń jẹ́ Wasiu ti ń bá ní kí ń ṣ’àdúrà fún ẹ
(Ọkọ Yétúndé Ọlọ́hun gbọ́ mo lè ṣépè fún ẹ)
(Bo ṣe ń náwó f’ọ́mọdé pẹ̀lú àgbà yẹn)
To ń tún ayé èèyàn tí wọ́n rò pé ó ti bàjẹ́ tán ṣe)
(Á máa yẹ ẹ́ kò dẹ̀ ní yẹ̀ sílẹ̀ fún ẹ)
( Áísìkí tí wọ́n fi ń p’éèyàn l’ọ́lọ́lá o)
(Bàbá lókè kó bá mi jogún ẹ̀ fún ẹ)
Olùgbàyè Wese ọ̀rẹ́ mi
(Riha Entertainment bàbá Rihanatu mi)
(Èèyàn kósílé ọkọ Bọ́lá Aliya mi)
(Kósílé hotel lọ́nà Sángo ìyànà yẹ́sí)
(Èèyàn Supretended police officer Ọpẹ́ifá)
(Rasheed Ọkọ Supretended ọkọ lọlá)
(Á máa yẹ ẹ́ kò dẹ̀ ní yẹ̀ sílẹ̀ fún ẹ)
( Áísìkí tí wọ́n fi ń p’éèyàn l’ọ́lọ́lá o)
(Bàbá lókè kó bá mi jogún ẹ̀ fún ẹ)
Àkámọ́ Fatai kì í ṣe ẹni àbùkù o
(Owó ọkọ Baraka kì í ṣe ẹni àrifín)
Ọkọ Olábísí Fadérera àdufẹ́
(Owó ọkọ Baraka kì í ṣe ẹni àrifín)
Bàbá ọ̀táòbáyọ̀mí bàbá Èjìrẹ́
(Owó ọkọ Baraka kì í ṣe ẹni àrifín)
Bàbá Adétúnjí o bàbá ti Mubarak
(Owó ọkọ Baraka kì í ṣe ẹni àrifín)
Bàbá Gbádébọ̀ bàbá Adéòtí Àkámọ́
(Owó ọkọ Baraka kì í ṣe ẹni àrifín)
Ẹní ní owu tẹ́rú Ọba Àkámọ́
(Ìwọ to tan’ná sí fìtílà òun l’òun mú)
Ẹní ní owu tẹ́rú Ọba Àkámọ́
(Ìwọ to tan’ná sí fìtílà òun l’òun mú)
Ìwọn to tan’ná sí fìtílà òun l’òun mú o
(Bó tẹ́rí sí àgbá òhun kò lè gbe)
Ìwọn to tan’ná sí fìtílà òun l’òun mú o
(Bó tẹ́rí sí àgbá òhun kò lè gbe)
Ó ń tó ri, ó ń yùn’mù
Ọmọ òró gbà, lékèsegbà
Ọmọ Olú ńlá àgbóderè
Ẹ fori dá’rí ọlá
Fori ilẹ̀ ọrọ̀
Wọ́n kì í f’ori ṣe’ré
(Ó ń tó ri, ó ń yùn’mù)
(Ọmọ òró gbà, lékèsegbà)
(Ọmọ Olú ńlá àgbóderè)
(Ẹ fori dá’rí ọlá)
(Fori ilẹ̀ ọrọ̀)
(Wọ́n kì í f’ori ṣe’ré)
Ó ń tó ri, ó ń yùn’mù
Ọmọ òró gbà, lékèsegbà
Ọmọ Olú ńlá àgbóderè
Ẹ fori dá’rí ọlá
Fori ilẹ̀ ọrọ̀
Wọ́n kì í f’ori ṣe’ré
(Ó ń tó ri, ó ń yùn’mù)
(Ọmọ òró gbà, lékèsegbà)
(Ọmọ Olú ńlá àgbóderè)
(Ẹ fori dá’rí ọlá)
(Fori ilẹ̀ ọrọ̀)
(Wọ́n kì í f’ori ṣe’ré)
Àkámọ́ mi Fatai Ẹkùn ọmọ ẹkùn
Tó fín torí torí
Ọmọ ẹkùn, tó fín tìrù tìrù
F’ori dá’rí ọlá
Fori ilẹ̀ ọrọ̀
Wọ́n kì í f’ori ṣe’ré
Ó ń tó ri, ó ń yùn’mù)
(Ọmọ òró gbà, lékèsegbà)
(Ọmọ Olú ńlá àgbóderè)
(Ẹ fori dá’rí ọlá)
(Fori ilẹ̀ ọrọ̀)
(Wọ́n kì í f’ori ṣe’ré)
Written by: Okunola Saheed