Similar Songs
Credits
PERFORMING ARTISTS
King Dr. Saheed Osupa
Performer
Okunola Saheed
Drums
COMPOSITION & LYRICS
Okunola Saheed
Songwriter
PRODUCTION & ENGINEERING
Okunola Saheed
Producer
Lyrics
Saidon P wonder
Mr Marvelous
Oba orin globally iwo logo Fuji
(Saidon P wonder)
(Mr Marvelous)
(Oba orin globally ìwọ lògo Fújì o)
Saidon P wonder
Mr Marvelous
Ọba orin globally ìwọ lògo Fújì
(Saidon P wonder)
(Mr Marvelous)
(Ọba orin globally ìwọ lògo Fújì o)
Ọba orin globally ìwọ lògo àgbáyé
(Ọba orin globally ìwọ lògo Fújì o)
Ọba orin globally ìwọ lògo àgbáyé o
(Ọba orin globally ìwọ lògo Fújì o)
Ẹ fi mí sílẹ̀, ẹ jẹ́ n jayé mi
Ẹ má pa Fújì music èmi lògo Fújì
(Saidon P wonder)
(Mr Marvelous)
(Ọba orin globally ìwọ lògo Fújì o)
Àní ẹ fi mí sílẹ̀, ẹ jẹ́ n jayé mi
Ẹ má pa Fújì music, èmi lògo Fújì
(Saidon P wonder)
(Mr Marvelous)
(Ọba orin globally ìwọ lògo Fújì o)
Ọba orin globally ìwọ lògo àgbáyé o
(Ọba orin globally ìwọ lògo Fújì o)
Èmi ò mà mọ orin tá fi wé Fújì Music
Afi percussions tó wà very melodious
(Èmi ò mà mọ orin tá fi wé Fújì Music)
(Afi percussions tó wà very melodious)
Fújì is the most popular lára the genre of music
Àwọn Yorùbá wa tí wọ́n ń fi sábà ṣe àríyá
(Èmi ò mà mọ orin tá fi wé Fújì Music)
(Afi percussions tó wà very melodious)
Àwọn tí ò tún sí nílé, tí wọ́n ń bẹ ní diaspora
Ní gbogbo àgbáyé wọ́n ń sọ pé Fújì music
Òhun làwọn ń jó ní gbogbo òde àríyá
(Èmi ò mà mọ orin tá fi wé Fújì Music)
(Afi percussion tó wà very melodious)
Atótó arére, ayé ń sọ pé Òṣùpá ò mu léré
Wọ́n ní ibo ló ń darí Fújì yìí lọ o
Ibi témi ń darí Fújì yìí lọ o
Ó kọjá ibi tí ẹ̀yin ń rò o o
(Arabic recitation)
Mo ri lójú oró ó bẹ̀ mí níṣẹ́
Mo rí agbájélọlá Barrister o
Ó ní kí n má wo eré Fújì yìí ń ran o
Kí n múra kó tún máa tẹ̀ síwájú
Ó fún mi lágbádá orin pẹ̀lú bùbá iyì
Ó ní n mú ṣòkòtò, m’ómele m’álùkínbà
Àlùkíǹbà orin tó jẹ etí ní gbèsè
Ó ní Akóredé mo fẹ́ ko jẹ́ káyé mọ̀
(P’ọ́mọ agbájé ló relé o, pé Fújì mi ò lọ)
P’ọ́mọ agbájé ló relé o, pé Fújì mi ò lọ o
(P’ọ́mọ agbájé ló relé o, pé Fújì mi ò lọ)
Àyìndé o! Àyìndé o!
Ọmọ agbájé ló relé o agbájé ló relé, pé Fújì mi ò lọ o
(Ọmọ agbájé ló relé o, pé Fújì mi ò lọ)
Ọba Ọlọ́hun tó lèní o, ó ni tomorrow
Ọba ìgbà gbogbo ọjọ́ pẹ̀lú oṣù
Ṣe ìkẹ́ ẹ f’Áyìndé fi sí alujanna rẹ
Ṣèkẹ́ f’Áyìndé o fi sí alujanna rẹ o
(Ṣe ìkẹ́ ẹ f’Áyìndé fi sí alujanna rẹ)
Torí Àyìndé mọ̀ da, Ọlọ́ládé mà ní ìwà
Ó bọ̀wọ̀ fún àgbà, ó tún da s’ọ́mọ kékèké
Torí ìdí èyí o, fi sí àyè onídẹ̀ra
Torí èyí o, fi sáyè onídẹ̀ra o
(Torí ìdí èyí o, fi sí àyè onídẹ̀ra)
Ló jẹ́ n sọ pé ìmísí Àyìndé Ògún ò kú o, musically ó tún ń mí
(Ìmísí Àyìndé Ògún ò kú o, musically ó tún ń mí)
Àní sẹ́ ìmísí Àyìndé Ògún ò kú musically ó tún ń mi
(Ìmísí Àyìndé Ògún ò kú o, musically ó tún ń mí)
Ó ṣì wà ní existence to bá ti ní ìgbàgbọ́
Ó ṣì wà ní existence to bá ti ní ìgbàgbọ́
Á gbé ẹ wọ̀ lójijì tó bá gbà fún Barry
Á gbé ẹ wọ̀ lójijì tó bá gbà fún Barry o
Torí pé Ìmísí Àyìndé Ògún ò kú o, musically ó tún ń mí
(Ìmísí Àyìndé Ògún ò kú o, musically ó tún ń mí)
Ó ṣì wà ní existence to bá ti ní ìgbàgbọ́
Ó ṣì wà ní existence to bá ti ní ìgbàgbọ́
Á gbé ẹ wọ̀ lójijì tó bá gbà fún Barry
Á gbé ẹ wọ̀ lójijì tó bá gbà fún Barry o
Torí pé Ìmísí Àyìndé Ògún ò kú o, musically ó tún ń mí
(Ìmísí Àyìndé Ògún ò kú o, musically ó tún ń mí)
Mo fẹ́ ko gbà wí pé Fújì music yìí o everlasting lorin mi
(Gbà wí pé Fújì music yìí o everlasting lorin mi)
Good music raw lyrics kò ní artificial nínú
Good music raw lyrics kò ní artificial nínú
Wá tọwò ko le mọ̀ p’ólóyin ládùn gan
Wá tọwò ko le mọ̀ p’ólóyin ládùn gan o
Mo fẹ́ ko gbà wí pé Fújì music yìí o everlasting lorin mi
(Gbà wí pé Fújì music yìí o everlasting lorin mi)
Torí wí pé, I prefer Fújì music yìí to other genres of music
( I prefer Fújì music yìí to other genres of music)
Gentlemen tó classy to bá bi wọ́n léèrè
Their preference in music wà á ró’rin Fújì ni
Ló jẹ́ n sọ pé I prefer Fújì music yìí to other genres of music
(I prefer Fújì music yìí to other genres of music)
Igúnnugún ṣíwájú ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́ tẹ̀le
Igúnnugún ṣíwájú ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́ tẹ̀le
Ká fi ìmúra jọ àlùbọ́sà ní pele ní pele
Ṣèbí wọ́n sọ pé bí a ṣe ń rìn la ṣe máa ń ko ni
Èwo ni ká kan àkànpọ̀ gẹ́gẹ́ bí aáyán
Ẹ má fi aṣọ ìwọ́lẹ̀ wé aṣọ àmúròde
Ẹ má fi aṣọ ìwọ́lẹ̀ wé aṣọ àmúròde
Ẹ má fi ọ̀rẹ́ aláṣìírí wé dábẹ̀-n yànkọ
Ẹ má fi ọ̀rẹ́ aláṣìírí wé dábẹ̀-n yànkọ
Ọ̀rọ̀ àṣírí ilé o má ma sọ́ mọ́ níta
Ọ̀rọ̀ àṣírí inú ilé o má ma sọ́ mọ́ níta
Ẹ má fi ọmọge ọlọ́rọ̀ ajé wé aya àmúṣẹ̀yẹ
Ẹ má fi ọmọge ọlọ́rọ̀ ajé wé aya àmúṣẹ̀yẹ
Torí kò tí ì ráyè láti ládé lórí
Ó lè má ì tíì ráyè láti ládé lórí
Ṣé ẹ rí àti kékeré mo ti fẹ́ràn motor gan
Mo má ń crave fún jamubi tó new gan
(Wọ́n wá ní ọ̀pọ̀ èrò kìí ṣe motor fún ẹnìkan)
(Tí ǹ bá sí nílé wọ́n á fi k’érò lẹ́yìn mi)
(Má sọ sọ̀ kí n sọ̀ motor ayé ni tì ẹ nìkan)
Láti kékeré mi náà ni
Láti kékeré mo ti fẹ́ràn motor gan
(Mo má ń crave fún jamubi tó new gan)
(Wọ́n wá ní ọ̀pọ̀ èrò kìí ṣe motor fún ẹnìkan)
(Tí ǹ bá sí nílé wọ́n á fi k’érò lẹ́yìn mi)
(Má sọ sọ̀ kí n sọ̀ motor ayé ni tì ẹ nìkan)
Mo wá ní upgrading tí mo fẹ́ fun kò ní jọ bus
(Mà á fun ní pimping tó máa fi jọ Ferrari ni)
(Wọ́n ní kó jọ Royce, kó jọ Lamborghini gan)
(Ọ̀pọ̀ èrò kìí ṣe motor fún ẹnìkan)
(Tí ń bá sí nílé wọ́n á fi k’érò lẹ́yìn mi)
(Má sọ sọ̀ kí n sọ motor ayé ni tì ẹ nìkan)
Mo ní upgrading tí mo fẹ́ fun kò ní jọ bus
(Mà á fun ní pimping tó máa fi jọ Ferrari ni)
(Wọ́n ní kó jọ Royce, kó jọ Lamborghini gan)
(Ọ̀pọ̀ èrò kìí ṣe motor fún ẹnìkan)
(Tí ń bá sí nílé wọ́n á fi k’érò lẹ́yìn mi)
(Má sọ sọ̀ kí n sọ motor ayé ni tì ẹ nìkan)
Á jẹ́ pé èèyàn bí danfo gan lójú ẹ̀ ò gbé ibìkan
(Èèyàn bí i car ṣá ni ojú kan làdá ń ní)
(O ti ra ọ̀pọ̀ èrò to bá fẹ́ wọn lóbìnrin)
(O ti ra ọ̀pọ̀ èrò to bá fẹ́ wọn lọ́kùnrin)
(Tó ò bá sí nílé wọ́n á fi k’érò lẹ́yìn ẹ)
(Má sọ sọ̀ kí n sọ̀ motor ayé ni tì ẹ nìkan)
Ṣẹ rí eyin olówó ní Nàìjíríà yìí o
(Èyí olówó wọ́n fi ń jẹ chicken ni)
(Eyin olòṣì ní party o opener ni)
(Tí wọ́n bá lọ sí Family meeting tí wọ́n ṣ’òde)
(Eyín tálíkà ni wọ́n ma ń padà fi ṣí ọtí ó)
Ìgbà tí ò bá ní capacity àti náwó
Ọlọ́hun má ta wá lóṣì o
Òṣì ò da,
(Eyín olówó wọ́n fi ń jẹ chicken ni)
(Èyí olòṣì ní party o opener ni)
(Tí wọ́n bá lọ sí Family meeting tí wọ́n ṣ’òde)
(Èyí tálíkà ni wọ́n ma ń padà fi ṣí ọtí o)
(Ìgbà tí ò bá ní capacity àti náwó)
Ṣèbí ìyàwó tálákà ló ma ń se’bẹ̀ ní party
(Ní party ńlá tó yẹ kí wọ́n pe caterer fún)
(Á di alámàlà, á di ọlọ́fadà aláta)
(Ní party family tó yẹ kí wọ́n máa dìjọ náwó)
(Ìgbà tí ò bá ní capacity àti náwó)
Ìyàwó tálákà ni
ìyàwó tálákà ló ma ń se’bẹ̀ ní party
(Ní party ńlá tó yẹ kí wọ́n pe caterer fún)
(Á di alámàlà, á di ọlọ́fadà aláta)
(Ní party family tó yẹ kí wọ́n máa dìjọ náwó)
(Ìgbà tí ò bá ní capacity àti náwó)
To bá ti wá ń yájú sí ẹni tó jù ẹ́ lọ
(Àwọn ọmọ ìgboro, wọ́n á máa wá ta whining fún ẹ)
(Wọ́n á ní wọ́n ń dín ẹyin lọ́wọ́)
(Ṣo gbọ́ máa jẹ bread ẹ lọ)
(Àbí o máa jẹ iṣu àti ẹyin kí wọ́n dín yamarita fún ẹ)
(Tí yamarita bá jinna, o ṣì máa jẹ ìyà ẹ)
To bá ti jẹ́ ọmọ tó bàjẹ́ o
To bá ti wá ń yájú sí ẹni tó jù ẹ́ lọ
(Àwọn ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà, wọ́n á máa wá ta whining fún ẹ)
(Wọ́n á ní wọ́n ń dín ẹyin lọ́wọ́)
(Ṣo gbọ́ máa jẹ bread ẹ lọ)
(Àbí o máa jẹ iṣu àti ẹyin kí wọ́n dín yamarita fún ẹ)
(Tí yamarita bá jinna, o ṣì máa jẹ ìyà ẹ)
Ọmọge ò mẹ́rù’lẹ̀, ó sọ nípa roma roma
(Romantic lo fẹ́ sọ ni àbí tẹwó)
(Ṣé mo jẹ́ bí alájọ lóṣoṣù tí wọ́n máa kó)
(Tẹwó báwo ṣe mo rọmi sápò ni)
(Bóyá ojú ló ń tì mí lé mi tí mo gọ̀ tẹwó kọ́)
(Mo ti ń tẹ̀ẹ́, wá fi iyán jẹ tẹ̀tẹ̀ ni)
Ọmọge wá o funny gan
O fẹ́ máa mú àgbàlagbà ṣe’ré
(O ò mẹ́rù’lẹ̀, sọ nípa roma roma)
(Romantic lo fẹ́ sọ ni àbí tẹwó)
(Ṣé mo jẹ́ bí alájọ lóṣoṣù tí wọ́n máa kó)
(Tẹwó báwo ṣe mo rọmi sápò ni)
(Bóyá ojú ló ń tì mí lé mi tí mo gọ̀ tẹwó kọ́)
(Mo ti ń tẹ̀ẹ́, wá fi iyán jẹ tẹ̀tẹ̀ ni)
Ṣe èyí to ó ṣe
(Jẹ́ ka tètè mọ̀ o)
(Má fi ìgbàgbọ́ ẹ dọ́la)
(Ìyàwó to fẹ́ fẹ́ o lo mú bi ọ̀rẹ́bìnrin)
(Ohun to fẹ́ jẹ yó ni láké o dẹ̀ fi ń run’mú)
(Ilẹ̀ ọlọ́ràá to rí to sọ pé ó wu ìwọ)
(Bó ṣe ń wo ẹrú ló ṣe ń wo ọmọ ní ibì kan)
(Kó má di pé aṣálẹ̀ ìlú lo fẹ́ padà gbin iṣu sí)
Ṣe èyí to ó ṣe
(Jẹ́ ka tètè mọ̀ o)
(Má fi ìgbàgbọ́ ẹ dọ́la)
(Ìyàwó to fẹ́ fẹ́ o lo mú bi ọ̀rẹ́bìnrin)
(Ohun to fẹ́ jẹ yó ni láké o dẹ̀ fi ń run’mú)
(Ilẹ̀ ọlọ́ràá to rí to sọ pé ó wu ìwọ)
(Bó ṣe ń wo ẹrú ló ṣe ń wo ọmọ ní ibì kan)
(Kó má di pé aṣálẹ̀ ìlú lo fẹ́ padà gbin iṣu sí)
Ọ̀rọ̀ ọkùnrin obìnrin láyé swimming pool ni
Torí pé odò tí tẹrú tọmọ ń wẹ̀ ni)
(Èèyàn ò ní béèrè pé ta ló ti kọ́’ wẹ̀ o)
(Èèyàn ò ní béèrè pé ta ló máa wẹ̀ tí n bá lọ)
(To bá ń béèrè tẹ́lẹ̀, wọ́n á padà purọ́ ni)
(Kò need lẹ́yìn pé kó o kàn máa wẹ̀ lọ)
Ọ̀rọ̀ ọkùnrin obìnrin láyé swimming pool ni
Torí pé odò tí tẹrú tọmọ ń wẹ̀ ni)
(Èèyàn ò ní béèrè pé ta ló ti kọ́’ wẹ̀ o)
(Èèyàn ò kí ń béèrè pé ta ló máa wẹ̀ tí n bá lọ)
(To bá ń béèrè tẹ́lẹ̀, wọ́n á padà purọ́ ni)
(Kò need lẹ́yìn pé kó o kàn máa wẹ̀ lọ)
Èèyàn mi Akeem Badmus mi
Baddy Oosha wọ́n ri wọ́n da mọ̀ o
(Ìwọ lọ béèrè si)
(Oosha Music Empire tí gbogbo ayé mọ̀ ni)
(Ìgboro ńlá tó lọ far far ni)
(Connect ńlá gbe súnmọ banker ni)
(Fi update sẹ́ orúkọ Baddy ń jáwó)
(Baddy ò dédé fojú d’ẹkùn Lion ni)
Baddy Oosha wọ́n ri wọ́n da mọ̀ o
(Ìwọ lọ béèrè si)
(Oosha Music Empire tí gbogbo ayé mọ̀ ni)
(Ìgboro ńlá tó lọ far far ni)
(Connect ńlá gbe súnmọ banker ni)
(Fi update sẹ́ orúkọ Baddy ń jáwó)
(Baddy ò dédé fojú d’ẹkùn Lion ni)
Èèyàn Da real home Yusufu Amuda
(Olówó èkó bàbá Fuhad mi)
(Some money t’áwọn ayé ń sọ bàbá olówó)
(Èèyàn ẹlẹlẹ Meiko ọmọ tó ga jù lábà yìí)
(Olako motors ló le lórí Island jù)
(Ọba Luxury nínú ká lọ o lẹ lẹ lẹ)
Baddy èèyàn Da real o
Èèyàn Da real home Yusufu Amuda
(Olówó èkó bàbá Fuhad mi)
(Some money t’áwọn ayé ń sọ bàbá olówó)
(Èèyàn ẹlẹlẹ Meiko ọmọ tó ga jù lábà yìí)
(Olako motors ló le lórí Island jù)
(Ọba Luxury nínú ká lọ o lẹ lẹ lẹ)
Èèyàn Tunde T pain
(Èèyàn Yusufu ọmọ Alhaja ní Istanbul)
(Èèyàn àlàyé ọlọ́rọ́ Ọ̀túnba Cash mi)
(Èèyàn Belodus, Bell homes èèyàn jẹ́jẹ́)
(Jẹ́jẹ́ properties ọmọ Joshua Akọgun)
Èèyàn Tunde Baddy Oosha o
Èèyàn Tunde T pain
(Èèyàn Yusufu ọmọ Alhaja ní Istanbul)
(Èèyàn àlàyé ọlọ́rọ́ Ọ̀túnba Cash mi)
(Èèyàn Belodus, Bell homes èèyàn jẹ́jẹ́)
(Jẹ́jẹ́ properties ọmọ Joshua Akọgun)
Ọmọ Akínbọ̀bọ́lá Agboolá mi (Bobby Ọba)
(CEO níbi ká ma sọ ààbọ̀ ọgbọ́n)
(Aláṣẹ Rattlegather tó ni car hire méjì pọ̀)
(Èèyàn Awótúndé RMD mi Jamiu mi)
(Ọmọ Awótúndé Ria luxe construct mi)
( Logistics Company ó pọ̀ gan)
Bọ̀bọ́lá mi Bobby mi
Èèyàn b a mà ti wà ti pẹ́
Ọmọ Akínbọ̀bọ́lá Agboolá mi (Bobby Ọba)
(CEO níbi ká ma sọ ààbọ̀ ọgbọ́n)
(Aláṣẹ Rattlegather tó ni car hire méjì pọ̀)
(Èèyàn Awótúndé RMD mi Jamiu mi)
(Ọmọ Awótúndé Ria luxe construct mi)
( Logistics Company ó pọ̀ gan)
Ọ̀gá ni ládiméjì nínú onírin (fatai mi)
(Ọkọ Adéjọkẹ́ owó bàbá Maliki mi)
(Bestlink investment kò lẹ́lẹ́gbẹ́)
(Ọmọ olórò orò-àìgbejẹ)
(Ọmọ Òrìṣà dákun jẹ́ kí n dàbí onílé yìí)
(Ẹ ba dòwò pọ̀ k’ájé wá kẹ lè ré’rè jẹ)
(Torí òun ni transformer fún àwọn onírin ìbẹ̀jù lekki)
Fatai Ọládiméjì mi
Ọ̀gá ni ládiméjì nínú onírin (fatai mi)
(Ọkọ Adéjọkẹ́ owó bàbá Maliki mi)
(Bestlink investment kò lẹ́lẹ́gbẹ́)
(Ọmọ olórò orò-àìgbejẹ)
(Ọmọ Òrìṣà dákun jẹ́ kí n dàbí onílé yìí)
(Ẹ ba dòwò pọ̀ k’ájé wá kẹ lè ré’rè jẹ)
(Torí òun ni transformer fún àwọn onírin ìbẹ̀jù lekki)
Èèyàn Èjìrẹ́ onírin àlàyé onírin lọ́nà Ajah
(Èèyàn Lukuman Shittu tó padà jẹ alága)
(Chairman gbogbo truck and cargo ni)
(Ọkọ Ọládùnní mi Baliki)
(Santalo all in gbogbo t’Apapa)
Èèyàn t’Èjìrẹ́ mi náà ni
Èèyàn Èjìrẹ́ o onírin àlàyé onírin lọ́nà Ajah
(Èèyàn Lukuman Shittu tó padà jẹ alága)
(Chairman gbogbo truck and cargo ni)
(Ọkọ Ọládùnní mi Baliki)
(Santalo all in gbogbo t’Apapa)
Riliwanu Cooler mi, Riliwanu Cooler má ri fín o (Ọ̀gá mà ni)
(Nínú elépo ní’jọrá ba yaro ba)
(Olórí ọ̀dọ̀ Riliwanu Akoi kudi)
(Ọmọ Sagunbadi arówó rọjà òkùn lọ́rà)
(Ọkọ Shukura owó bàbá Mustapha)
(Èèyàn Ẹlẹ́ṣin Bọ́lájí awo Ọba Shefield mi)
(Ẹ̀gbọ́n Yusufu cooler ṣá ni èèyàn Ẹwẹlẹ)
Riliwanu Cooler mi, Riliwanu Cooler má ri fín o (Ọ̀gá mà ni)
(Nínú elépo ní’jọrá ba yaro ba)
(Olórí ọ̀dọ̀ Riliwanu Akoi kudi)
(Ọmọ Sagunbadi arówó rọjà òkùn lọ́rà)
(Ọkọ Shukura owó bàbá Mustapha)
(Èèyàn Ẹlẹ́ṣin Bọ́lájí awo Ọba Shefield mi)
(Ẹ̀gbọ́n Yusufu cooler ṣá ni èèyàn Ẹwẹlẹ)
Doro Bucci mi, Doro Bucci Amuda o yáyì gan
(Ọkọ Alimo Aláúsá mi Bàbá mẹ́ta)
(Kò ní fi ẹ́ lẹ̀ Ọba tó ti wà lẹ́yìn ẹ)
(Ọkọ ọ̀gbàmùgbámú ojú ọ̀run kò ṣe é gbámú)
(Èèyàn Kú lé àlàyé Sir Poly mi)
(Èèyàn Ìgboho Actor Májà Sunday mi)
(Igi eléèrà bí wọ́n gbe, wọ́n á gbe jù sílẹ̀ ni)
Doro Bucci mi, Doro Bucci Amuda o yáyì gan
(Ọkọ Alimo Aláúsá mi Bàbá mẹ́ta)
(Kò ní fi ẹ́ lẹ̀ Ọba tó ti wà lẹ́yìn ẹ)
(Ọkọ ọ̀gbàmùgbámú ojú ọ̀run kò ṣe é gbámú)
(Èèyàn Kú lé àlàyé Sir Poly mi)
(Èèyàn Ìgboho Actor Májà Sunday mi)
(Igi eléèrà bí wọ́n gbe, wọ́n á gbe jù sílẹ̀ ni)
Ìgboho Sunday Akínkanjú ni actor ni
(Gbogbo host fẹnu jagun wọ́n ń yọ̀ ni)
(Bílé bá dá tí ogun dé ọkùnrin mà ni)
(Bílé ò tún dá ó tó gbangba sùn lọ́yẹ́)
(Ikú apọlọpọ́lọ̀ má ri fín ọkùnrin ogun)
Ẹ ẹ̀ lógun ní èkó, ẹ ẹ̀ lógun lékòó
Ẹ ní ẹ lógun níbàdàn, ṣé jagunjagun inú ilé yín lẹ̀yin
Ṣé ogun jẹ́ ludo, ṣé ó jọ ọpọ́n ayò lọ́dọ̀ yín
Ṣ’ógun jẹ́ àwàdà, ṣé ó jọ comedy lóju yín
Akọgun Délé Joshua mi
(Akọgun Délé Joshua Ọlọ́hun gbọ́ iyì ẹ pọ̀ si)
(Májẹ̀óbàjẹ́ l’Áyégbé Èkìtì)
(Ọkọ yèyé Májẹ̀óbàjẹ́)
(Èèyàn Adé Balógun Akínrógun bàbá ń Dodo)
(Èèyàn Ọláyíwọlá ní Sagamu Idris mi)
(Èèyàn Elder Samuel Baṣọ̀run)
(Ìmùlẹ̀ bàbá Olóyè dé mi Elder mi)
(Èèyàn Ọ̀túnba Elder tọ́ a tẹ́lẹ̀ mi)
(Délé ọkọ Olúwatóyìn Anjorin Akọgun)
Old Sojà ló ní mi ò fọ́ fún wọn, mi ò rán wọn
Ọba orin làwa mọ̀ l’ólórin
Èèyàn Lukuman ọ̀rẹ́ mi
Ó l’Ọba orin làwa ń jẹ
Ọba orin mi ò gbọ́ ikú ẹ
O ò rá’re, o ò wálẹ̀ tí bèlà ó fi fọn
(Mi ò gbọ́ ikú ẹ)
(O ò rá’re, o ò wálẹ̀ tí fìlà ó fi fọn)
O ò tàràkà, O ò ṣẹ̀sín
O ò gbowó lápò láti jẹun
(O ò tàràkà, O ò ṣẹ̀sín)
(O ò gbowó lápò láti jẹun)
Ọmọ Ọlájukú Lokoso
Ọkọ Adija Kubura
Àjíún Adija Kubura
Aláṣẹ Azeezatu International ní New York City
O ò tàràkà, O ò ṣẹ̀sín
O ò gbowó lápò láti jẹun
(O ò tàràkà, O ò ṣẹ̀sín)
(O ò gbowó lápò láti jẹun)
Olúlàdé yìí l’ówódé o
Ọkọ Kíkẹ̀lọmọ Basiratu
Bàbá Ọlámidé bàbá Hannah
Ìmùlẹ̀ Olúọmọ Musiliu
ò tàràkà, O ò ṣẹ̀sín
O ò gbowó lápò láti jẹun
(O ò tàràkà, O ò ṣẹ̀sín)
(O ò gbowó lápò láti jẹun)
Láti Amsterdam lọ sí Germany
(Bàbá o ṣé, o ṣé Ọlọ́hun mi bàbá o ṣé)
Kennydina mà ló gbé wa wá o
(Bàbá o ṣé, o ṣé Ọlọ́hun mi bàbá o ṣé)
Èèyàn DJwheel gbogbo ti Fontaine
(Bàbá o ṣé, o ṣé Ọlọ́hun mi bàbá o ṣé)
MC Musibau ọmọ Oyètúndé o
(Bàbá o ṣé, o ṣé Ọlọ́hun mi bàbá o ṣé)
Èèyàn bàbá Jersey ọmọ Ògúnyẹmí o
(Bàbá o ṣé, o ṣé Ọlọ́hun mi bàbá o ṣé)
Pijo Italo o ṣé mo dúpẹ́ o
(Bàbá o ṣé, o ṣé Ọlọ́hun mi bàbá o ṣé)
Rasaki Embassy ẹ ṣé mo dúpẹ́ o ṣé o
(Bàbá o ṣé, o ṣé Ọlọ́hun mi bàbá o ṣé)
Biliqiyu Ọlábámijí o
(Bàbá o ṣé, o ṣé Ọlọ́hun mi bàbá o ṣé)
Written by: Okunola Saheed