Featured In

Credits

PERFORMING ARTISTS
King Dr. Saheed Osupa
King Dr. Saheed Osupa
Performer
Okunola Saheed
Okunola Saheed
Drums
COMPOSITION & LYRICS
Okunola Saheed
Okunola Saheed
Songwriter
PRODUCTION & ENGINEERING
Okunola Saheed
Okunola Saheed
Producer

Lyrics

Ọ̀nà kan ní’kú, ṣèbí ọ̀nà kan ni iyè
(Saheed Ṣé ẹ fẹ́ gbọ́)
Ọ̀nà kan ṣá ni ikú ṣèbí ọ̀nà kan ni ìyè
(Saheed, ṣé ẹ fẹ́ gbọ́ o)
Ìyè la fi wá, ti kú la fi ń padà
(Kò ní yẹ̀, kò ní sé)
Ọ̀nà ìyè la fi wá, ti kú la fí ń padà
(Kò ní yẹ̀, kò ní sé o)
Ọ̀run ṣá nílé ṣèbí ayé lọjà
(Ẹ má mà ṣìmí gbọ́)
Ọ̀run ṣá nílé ṣèbí ayé lọjà
(Ẹ má mà ṣìmí gbọ́)
Ọ̀run ṣá nílé ṣèbí ayé lọjà
(Ẹ má mà ṣìmí gbọ́ o)
Àjò ò ní san wá, ká má relé lọ sùn
(Ìyẹn mà di dandan)
Ah àjò òní san wá ká má relé lọ sùn
(Ìyẹn mà di dandan o)
The Organically end is Fújì
(Òṣùpá làgbẹ̀dẹ orin)
The Organically end is Fújì
(Òṣùpá làgbẹ̀dẹ orin)
Kò láfiwé ni incomparable
(Òṣùpá ò lẹ́lẹ́gbẹ́)
Kò mà láfiwé, the incomparable
(Òṣùpá ò lẹ́lẹ́gbẹ́ o)
Làwọn olọgbọ́n fi ní Òṣùpá sé o mọ̀
(Kàyéfì ọ̀rọ̀ ẹ jẹ́)
Làwọn tó lọ́gbọ́n fi ní Òṣùpá sé o mọ̀
(Kàyéfì ọ̀rọ̀ ẹ jẹ́)
You have become Oracle of music
(Deity Òòṣà orin)
You have become Oracle of music
(O ti di deity Òòṣà orin o)
Olúwakóredé ó, àtẹ́ẹ̀ká o niyùn ọlọ́lá o
Sálúbàtà ni iyùn ọlọ́rọ̀
Bá a bá gbéra ẹni níra àgbéjù Ọba ni wọ́n ń fi ni jẹ
Bí èèyàn bá pe ara rẹ̀ lólòṣì, wọ́n á ba de ládé
Ẹni bá pé ẹ ẹ̀ mọ̀ọ́ alára ìyà ìyà yẹn ló máa jẹ́
Tẹ̀tẹ̀ tí ò bá fẹ́ tẹ́ láwùjọ ẹ̀fọ́ o
Á yẹra fún ewékéwé ni àbí ẹ ò mọ̀
Rere lo bá ti ń ṣe, ìkà lo bá ti ń ṣe o
Má da dúró máa ṣé lọ
Gbogbo ohun to ṣe, o ṣé ni fún ra ẹ
Ọ̀rọ̀ yìí lọ̀rọ̀ tó ń jáde ṣá lẹ́nu afọ́jú
(Rere lo bá ti ń ṣe, ìkà lo bá ti ń ṣe o)
(Má da dúró máa ṣé lọ)
(Gbogbo ohun to ṣe, o ṣé ni fún ra ẹ)
(Ọ̀rọ̀ yìí lọ̀rọ̀ tó ń jáde ṣá lẹ́nu afọ́jú)
Bó bá jẹ́ owó lẹ bá fun
Kò ní dúpẹ́ pé ẹṣé o
Gbogbo ohunkóhun tẹ bá ti ń fún
Kò ní dúpẹ́ pé ẹṣé o
Á ní má da dúró máa ṣé lọ
Gbogbo ohun to ṣe, o ṣé ni fún ra ẹ
Ọ̀rọ̀ yìí lọ̀rọ̀ tó ń jáde ṣá lẹ́nu afọ́jú
(Rere lo bá ti ń ṣe, ìkà lo bá ti ń ṣe o)
(Má da dúró máa ṣé lọ)
(Gbogbo ohun to ṣe, o ṣé ni fún ra ẹ)
(Ọ̀rọ̀ yìí lọ̀rọ̀ tó ń jáde ṣá lẹ́nu afọ́jú)
Lọ́jọ́ kan bàbá olówó ọlọ́rẹ
Tó lọ f’áfọ́jú yẹn lọ́rẹ
Kò wá dúpẹ́ pé ẹṣé o
Ó ní Gbogbo ohun to ṣe
Má da dúró máa ṣé lọ, bo ṣé o ṣé ni fúnra ẹ
Ọ̀rọ̀ yìí lọ̀rọ̀ tó ń jáde ṣá lẹ́nu afọ́jú
(Rere lo bá ti ń ṣe, ìkà lo bá ti ń ṣe o)
(Má da dúró máa ṣé lọ)
(Gbogbo ohun to ṣe, o ṣé ni fún ra ẹ)
(Ọ̀rọ̀ yìí lọ̀rọ̀ tó ń jáde ṣá lẹ́nu afọ́jú)
Inú bá bí Bàbá yẹn
Ó ní ta bá fún ni lọ́rẹ
Ta bá gboore ọpẹ́ là ń ṣe e
Ìwọ fàìdúpẹ́ f’olóore ṣó da?
Ọ̀rọ̀ yìí mà ló jí ó létè, tó fẹ́ lọ lọ́gbọ́n
(Rere lo bá ti ń ṣe, ìkà lo bá ti ń ṣe o)
(Má da dúró máa ṣé lọ)
(Gbogbo ohun to ṣe, o ṣé ni fún ra ẹ)
(Ọ̀rọ̀ yìí lọ̀rọ̀ tó ń jáde ṣá lẹ́nu afọ́jú)
Lọ́jọ́ kan bàbá olówó ọlọ́rẹ
Ó gbé ejò kékeré ó wá fowó si
Ó gbe sí afọ́jú yẹn lápò o
Ọmọ Bàbá olówó ọlọ́rẹ ìyẹn wá ń darí bọ̀ lájò o
Ó fẹ́ f’áfọ́jú yẹn lọ́rẹ
Ejò tí bàbá gbé sápò afọ́jú ṣan lọ́wọ́
Ọ̀rọ̀ yìí
(Rere lo bá ti ń ṣe, ìkà lo bá ti ń ṣe o)
(Má da dúró máa ṣé lọ)
(Gbogbo ohun to ṣe, o ṣé ni fún ra ẹ)
(Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó ń jáde ṣá lẹ́nu afọ́jú)
È é ti jẹ́ gan tẹ wá ń hùwà ẹranko
Ẹ̀dá, è é ti jẹ́ gan tẹ wá ń hùwà ẹranko
Ìwà àbòsí ọwọ́ yín pọ̀ ẹ jáwọ́
Ọ̀tẹ̀ ṣe wá di ohun tí ẹ gbúdọ̀ tẹ pá mọ́
Ọlọ́hun Ọba ti mu yín ẹ̀yin ẹni ibi
(È é ti jẹ́ gan tẹ wá ń hùwà ẹranko)
(Ẹ̀dá, è é ti jẹ́ gan tẹ wá ń hùwà ẹranko)
(Ìwà àbòsí ọwọ́ yín pọ̀ ẹ jáwọ́)
(Ọ̀tẹ̀ ṣe wá di ohun tí ẹ gbúdọ̀ tẹ pá mọ́)
(Ọlọ́hun Ọba ti mu yín ẹ̀yin ẹni ibi)
Ẹ̀dá, è é ti jẹ́ gan tẹ wá ń hùwà ẹranko
Ẹ̀ jọ̀ọ́, è é ti jẹ́ gan tẹ wá ń hùwà ẹranko
Ìwà àbòsí ọwọ́ yín pọ̀ ẹ jáwọ́
Ọ̀tẹ̀ ṣe wá di ohun tí ẹ gbúdọ̀ tẹ pá mọ́
Ọlọ́hun Ọba ti mu yín ẹ̀yin ẹni ibi
(È é ti jẹ́ gan tẹ wá ń hùwà ẹranko)
(Ẹ̀dá, è é ti jẹ́ gan tẹ wá ń hùwà ẹranko)
(Ìwà àbòsí ọwọ́ yín pọ̀ ẹ jáwọ́)
(Ọ̀tẹ̀ ṣe wá di ohun tí ẹ gbúdọ̀ tẹ pá mọ́)
(Ọlọ́hun Ọba ti mu yín ẹ̀yin ẹni ibi)
Alákọrí f’ọwọ́ ara ẹ̀ ṣe ara ẹ̀
Àbí ẹ ò r’álákọrí fọwọ́ ara ẹ̀ ṣe ara ẹ̀
Kòtò ọ̀tá, to ló o gẹ́ jìn lo kósí
Ọlọ́hun ló mọ ẹjọ́ alábòsí yín dá
Ẹni d’eérú leérú yín tọ̀, ṣé ẹ ti ri?
(Alákọrí f’ọwọ́ ara ẹ̀ ṣe ara ẹ̀)
(Àbí ẹ ò r’álákọrí fọwọ́ ara ẹ̀ ṣe ara ẹ̀)
(Kòtò ọ̀tá, to ló o gẹ́ jìn lo kósí)
(Ọlọ́hun ló mọ ẹjọ́ alábòsí yín dá)
(Ẹni d’eérú leérú yín tọ̀, ṣé ẹ ti ri?

Ọ̀rẹ́ inú mo ko jẹ (ju ọ̀rẹ́ ojú yẹn lọ o)
Ọ̀rẹ́ n pá irọ́ ni (mi ò lè bá’yàn ṣe ò)
Àgbọ̀rín yín gba gbogbo (oko olóko jẹ́ o)
Ìwà yín tẹ rí yẹn (ò ṣe é fi wé tèmi o)
Gbogbo ohun táwọn ayé sọ pé ó da lèmi á máa ṣe
Gbogbo ohun táwọn ayé sọ pé ó da lèmi á máa ṣe
(Gbogbo ohun táwọn ayé sọ pé ó da lèmi á máa ṣe)

Aní gbogbo ohun táwọn ayé sọ pé ó da lèmi á máa ṣe o
(Gbogbo ohun táwọn ayé sọ pé ó da lèmi á máa ṣe)
Tí mo fi ní ẹ kíyè sọ́rọ̀ mi, ẹ̀yin ayé
Ọmú ìyá Màlúù, ní wọ́n ma ń fún Màlúù mu
(Ọmú èèyàn ló yẹ kí wọ́n máa fún èèyàn mu)
(Ayé wá ń fún ọmú ẹranko ságolo lọ́unje o fún ọmọdé)
(Wọn ò mọ̀ pẹ́ ẹ̀jẹ̀kẹ́jẹ̀ ni wọ́n ń fi sára ò fún ọmọdé)
(Ẹ̀jẹ̀ ẹranko ló ń di wàrà ẹranko)
(Ìdí ẹ̀ rèé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wùwà ẹranko)
Mo láyé ẹ kíyè sọ́rọ̀ mi, gbogbo ayé
Ọmú ìyá Màlúù, ní wọ́n ma ń fún Màlúù mu
(Ọmú èèyàn ló yẹ kí wọ́n máa fún èèyàn mu)
(Ayé wá ń fún ọmú ẹranko ságolo lọ́unje o fún ọmọdé)
(Wọn ò mọ̀ pẹ́ ẹ̀jẹ̀kẹ́jẹ̀ ni wọ́n ń fi sára ò fún ọmọdé)
(Ẹ̀jẹ̀ ẹranko ló ń di wàrà ẹranko)
(Ìdí ẹ̀ rèé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wùwà ẹranko)
Ṣùgbọ́n ayé ò wá mọ̀ pé lẹ́yìn àdàbà ẹyẹ oníwà tútù yẹn
(Àti ẹyẹlé ẹyẹ tó mọ rírì èèyàn)
(Tí kìí b’ónílé jẹ kó yẹrí bí ìṣòro bá dé)
(ìwà bi wèrè ló pọ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹranko)
(Ká f’olóore láṣọ ya ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀)
(Ètekéte láburú ejò ló nìyẹn)
(To bá láàánú jù to lọ gbé ọmọ ẹkùn kékeré)
(To gbe sábẹ́, to ní o fẹ́ tọ kó dàgbà)
(Tó bá d’ògìdán, á padà pani jẹ)
(Ìdí ẹ̀ rèé tí wọ́n fi ní ọmọ ẹkùn ẹkùn ni)
Àní ọ̀pọ̀ ẹ̀dá ò wá mọ̀ pé
(Lẹ́yìn àdàbà ẹyẹ oníwà tútù yẹn)
Àti ẹyẹlé ẹyẹ tó mọ rírì èèyàn)
(Tí kìí b’ónílé jẹ kó yẹrí bí ìṣòro bá dé)
(ìwà bi wèrè ló pọ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹranko)
(Ká f’olóore láṣọ ya ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀)
(Ètekéte láburú ejò ló nìyẹn)
(To bá láàánú jù to lọ gbé ọmọ ẹkùn kékeré)
(To gbe sábẹ́, to ní o fẹ́ tọ kó dàgbà)
(Tó bá d’ògìdán, á padà pani jẹ)
(Ìdí ẹ̀ rèé tí wọ́n fi ní ọmọ ẹkùn ẹkùn ni)
Ṣẹ rí arábìnrin kan ló ń sin ejò nínú ilé
(Ejò yẹn gùn bí ẹsẹ̀ bàtà)
(Ẹsẹ̀ bàtà méje, wọ́n jọ jí wọ́n jọ ń sùn ni)
(Ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú ló máa ń gbé oúnjẹ fún ejò yẹn)
(Ṣùgbọ́n ṣàdédé lóri pé ejò yìí ò jẹun)
(Ó wá lọ pé Dọ́kítà tó mọ nípa àwọn ẹranko)
Àní arábìnrin kan ló ń ṣe ejò nínú ilé
Ejò yẹn gùn bí ẹsẹ̀ bàtà)
(Ẹsẹ̀ bàtà méje, wọ́n jọ jí wọ́n jọ ń sùn ni)
(Ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú ló máa ń gbé oúnjẹ fún ejò yẹn)
(Ṣùgbọ́n ṣàdédé lóri pé ejò yìí ò jẹun)
(Ó wá lọ pé Dọ́kítà tó mọ nípa àwọn ẹranko)
Dọ́kítọ̀ yẹn wá dé o
Dọ́kítọ̀ yẹn dé, ó ṣe àyẹ̀wò ejò yẹn
Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tó rí pé èjò yẹn
Bi pé ó mọ̀ ọ́ mọ̀ f’ebi pa ara ẹ̀ sínú ilé
Kó le fi olówó ẹ̀ tó mọ̀ ṣe oúnjẹ àjẹyó
(Àní Dọ́kítọ̀ yẹn wá dé o)
(Dọ́kítọ̀ yẹn dé, ó ṣe àyẹ̀wò ejò yẹn)
(Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tó rí pé èjò yẹn)
(Bi pé ó mọ̀ ọ́ mọ̀ f’ebi pa ara ẹ̀ sínú ilé)
(Kó le fi olówó ẹ̀ tó mọ̀ ṣe oúnjẹ àjẹyó)
  
Ayé ni ọmọdé yìí má jà ó lóun fẹ́ na àgbà ní òkúta
(Ó ní ẹni tí ìwọ fẹ́ nà ní iṣẹ́ ṣe o rò pé ó gọ̀ ni)
(Ta ló ṣe òògùn ìlàyà fún ọmọ tí ò gbọ́ o)
(Ẹ gba nǹkan ọwọ́ ẹ̀, kí wọ́n sáré fi ṣe nǹkan fun)
Wọ́n ní ọmọdé yìí má jà o
Ìjàòdọlà, ìjà ò da
Ayé ni ọmọdé yìí má jà ó lóun fẹ́ na àgbà ní òkúta
(Ó ní ẹni tí ìwọ fẹ́ nà ní iṣẹ́ ṣe o rò pé ó gọ̀ ni)
(Ta ló ṣe òògùn ìlàyà fún ọmọ tí ò gbọ́ o)
(Ẹ gba nǹkan ọwọ́ ẹ̀, kí wọ́n sáré fi ṣe nǹkan fun)
T’ọmọ eku bá ń bá eku jà o
T’ọ́mọ ẹyẹ bá ẹyẹ jà
Tí wọ́n sọ pé ó ti tó
Tí ò gbà pé ó ti tó
(Wọ́n ní ẹ kó wọn sínú net, ẹ kó wọn sínú cage)
(Kó di cage fighting kí àwọn ayé mọ Champion)
(Ta ló ṣòògùn ìlàyà fún ọmọ tí ò gbọ́ o)
(Wọ́n á ní ẹ gba nǹkan ọwọ́ ẹ̀ , kí wọ́n sáré fi ṣe nǹkan fun)
Wọ́n ní ọ̀rọ̀ ló rí bó ṣe rí yìí
(Ìyá ọmọdé yìí dà o)
Ẹ pe ìyá ẹ̀ wá a fẹ́ mọ bó ṣe ṣé jàre
(Bó ṣe tọ ọmọ t’áyé ọmọ ṣe bàjẹ́ gan tó yìí)
(Kéèyàn tọ́mọ káyé ọmọ pinyìnkìn kò da)
Ọ̀rọ̀ àwọn àgbà Yorùbá mà ni
Tọ́rọ̀ bá kọjá àlà tán
Wọ́n ní ọ̀rọ̀ ló rí bó ṣe rí yìí
(Ìyá ọmọdé yìí dà o)
Ẹ pe ìyá ẹ̀ wá a fẹ́ mọ bó ṣe ṣé jàre
(Bó ṣe tọ ọmọ t’áyé ọmọ ṣe bàjẹ́ gan tó yìí)
(Kéèyàn tọ́mọ káyé ọmọ pinyìnkìn kò da)
Yaro èmọ̀ nínú ọlọ́rẹ tó sure ni
(Ẹni Ọlọ́run bá ran sí kan àgbákò ire)
(Kò need láti tún máa pè’pẹ̀ fún owó)
(Torí ó ti ńí àkọsílẹ̀ fún ẹni t’Ọba òkè ran sí)
(Ọkọ Ganiya nílùú Canada ẹ̀mí ọ̀gá)
(Bàbá Baraka bàbá ti Muhammed mi)
(Arabic recitation)
Allahu Sati féràn àwọn ọlọ́rẹ
Èèyàn mi Saheed Yaro mi
Yaro ẹmọ̀ nínú ọlọ́rẹ tó sure ni
(Ẹni Ọlọhun bá ran sí kan àgbákò ire)
(Kò need láti tún máa pè’pẹ̀ fún owó)
Torí ó ti ńí àkọsílẹ̀ fún ẹni t’Ọba òkè ran sí)
(Ọkọ Ganiya nílùú Canada ẹ̀mí ọ̀gá)
(Bàbá Baraka bàbá ti Muhammed mi)
(Arabic recitation)
(Allahu Sati féràn àwọn ọlọ́rẹ)
Ahmed essence Director fẹ́ràn Ọba orin ò débi pé
(Ó lọ́gbọ́n àti òye ń bẹ nínú Shiru wa)
(Àye ijó ọ̀tọ̀ ká fi orin ṣe àkàwé dúró)
(Ọba orin ò kọ̀ kìí ṣe olórin ṣá níbi kan)
(Ọkọ Biliki alága bàbá Mustapha)
(Àwọn Ahmed fẹ́ràn Ọba orin tìran tìran)
Ahmed essence Director mi
Essence Director fẹ́ràn Ọba orin ò débi pé
(Ó lọ́gbọ́n àti òye ń bẹ nínú Shiru wa)
(Àye ijó ọ̀tọ̀ ká fi orin ṣe àkàwé dúró)
(Ọba orin ò kọ̀ kìí ṣe olórin ṣá níbi kan)
(Ọkọ Biliki alága bàbá Mustapha)
(Àwọn Ahmed fẹ́ràn Ọba orin tìran tìran)
Ọlọ́hun ló ní ká fẹ o, kó ṣẹ bẹ́ẹ̀
(Bí èèyàn bá sọ pé kiní kan ò mà lè ṣe)
(Honorable Olújìmí mi Asagade)
(Chairman house committee local government Asagade)
(Àti Chieftaincy Affairs jákèjádò Ọ̀ṣun ló jẹ)
(Èèyàn Ẹgbẹ́nù déwálé mi speaker mi)
(Èèyàn ti Taofeek, tó jẹ́ K dollar tiwa ni)
Èèyàn Òṣùpá mi jerry mi
(Dabosi DBS auto àlàyé)
(Èèyàn lani bottle water o lasdam)
(Èèyàn much money mi Mosho Moshood mi)
(Òun lèèyàn Bíọ́lá ọlọ́rọ̀ mi)
(Èèyàn Yọ̀mí mi Sax Jerry ọmọ Salami mi)
(Dabosi DBS auto àlàyé)
(Èèyàn lani bottle water o lasdam)
(Èèyàn much money mi Mosho Moshood mi)
(Òun lèèyàn Bíọ́lá ọlọ́rọ̀ mi)
(Èèyàn Yọ̀mí mi Sax Jerry ọmọ Salami mi)
Sonakas Sunny ọmọ Dende ni
(Bakasiko ọkọ Kafayatu mi)
(Bàbá Ameera owó bàbá Khalid mi)
(Ó sún mọ́ Déńdè ló fi wá di èèyàn Ọba orin)
Ọmọ Sunny ọ̀rẹ́ mi
Sonakas Sunny ọmọ Dende ni
(Bakasiko ọkọ Kafayatu mi)
(Bàbá Ameera owó bàbá Khalid mi)
(Ó sún mọ́ Déńdè ló fi wá di èèyàn Ọba orin)
Cashier Sherrif owó Bàbá Sofia mi
(Èèyàn tapa Sulemona of London)
(Èèyàn babájídé ọmọ́balógun Ahmid mi)
(Èèyàn Omoye Babatunde London ni)
(Sherrif always ọmọ Okùnọlá ni)
Okùnọlá Sherrif mi, Cashier Sherrif owó Bàbá Sofia mi
(Èèyàn tapa Sulemona of London)
(Èèyàn babájídé ọmọ́balógun Ahmid mi)
(Èèyàn Omoye Babatunde London ni)
(Sherrif always ọmọ Okùnọlá mi)
Kàbírù Ajíshopẹ́ mi ọmọ Asípa
(Aláṣẹ Kabtol Hotel bàbá Olówó)
(Owó tí wọ́n mọ̀ tó pọ̀ tó ralẹ̀ tó kọ́lé)
(Tó tún bùáyà, tó dẹ̀ ń ṣe ohun mèremère)
(Ajíshọpẹ́ Kàbírù mi, Kàbírù Ajíshopẹ́ mi ọmọ Asípa
(Aláṣẹ Kabtol Hotel bàbá Olówó)
(Owó tí wọ́n mọ̀ tó pọ̀ tó ralẹ̀ tó kọ́lé)
(Tó tún bùáyà, tó dẹ̀ ń ṣe ohun mèremère)
Gbéra dìde ọ lọ́jọ́ ìbí ò ká jọ fi ijó bẹ
(Ìwọ mà la wá bá ṣe àjẹyọ̀ ta pé jọ)
(Kòsí ihun méjì to fẹ́ ṣe ò tó kọjá ọpẹ́)
(Dúpẹ́ gidi gan, ká lè fi mọ̀ pé o moore)
Gbéra dìde ọ lọ́jọ́ ìbí ò ká jọ fi ijó bẹ
(Ìwọ mà la wá bá ṣe àjẹyọ̀ ta pé jọ)
(Kòsí ihun méjì to fẹ́ ṣe ò tó kọjá ọpẹ́)
(Dúpẹ́ gidi gan, ká lè fi mọ̀ pé o moore)
Ọdún ń gorí ọdún kò sí ìyọnu
Ọjọ́ ń gorí ọjọ́ ko ko ko lara tún le
Kòsí ohun méjì to fẹ́ ṣe ò tó kọjá ọpẹ́)
(Dúpẹ́ gidi gan, ká lè fi mọ̀ pé o moore)
(Gbéra dìde ọ lọ́jọ́ ìbí ò ká jọ fi ijó bẹ
(Ìwọ mà la wá bá ṣe àjẹyọ̀ ta pé jọ)
(Kòsí ihun méjì to fẹ́ ṣe ò tó kọjá ọpẹ́)
(Dúpẹ́ gidi gan, ká lè fi mọ̀ pé o moore)
Adéjọkẹ́ Jọkẹ́ Onífádé
Aya Báyọ̀ Òṣíṣànyà, aláṣẹ Emmanuel homes
Bàbá Adé ìkẹ́ o ṣé ọmọ ikẹnne Eréke
Èèyàn t’Òyéwọlé Joseph ọkọ Tolúlọpẹ́
Èèyàn t’Adé ọmọga ọmọ fèyíṣará
Èèyàn Paul Igiti o l’Oclaoma mi
Èèyàn Doyin odu mi ò gbogbo Atlanta mi
(Gbéra dìde ọ lọ́jọ́ ìbí ò ká jọ fi ijó bẹ
(Ìwọ mà la wá bá ṣe àjẹyọ̀ ta pé jọ)
(Kòsí ihun méjì to fẹ́ ṣe ò tó kọjá ọpẹ́)
(Dúpẹ́ gidi gan, ká lè fi mọ̀ pé o moore)
Luxiria Construction Company tó ń talé
Àwọn làmìlaka l’Abuja
(Luxiria Construction Company tó ń talé)
(Àwọn làmìlaka l’Abuja)
MOK is okay, wọ́n mọ iṣẹ́
Luxiria àwọn làmìlaka l’Abuja
Luxiria Construction Company tó ń talé)
(Àwọn làmìlaka l’Abuja)
Project 5 ara ilé iṣẹ́
Tools and schedges ara ilé iṣẹ́
Metro Cribs ara ilé iṣẹ́
Developer gidi ṣá ni wọ́n
Bí wọ́n ṣe ń ta’lẹ̀ ni wọ́n ṣe ń ta’lé
Bàbá Fera, Bàbá Imran
Ọkọ Ramot bàbá Hamza mi
Luxiria construction company tó ń ta’lé
Àwọn làmìlaka l’Abuja
(Luxiria Construction Company tó ń ta’lé)
(Àwọn làmìlaka l’Abuja)
Ọ̀rọ̀ ti t’Akeem Shehu ọkọ Yétúndé
Ẹ̀jẹ̀ Moruf Abass ọkọ Festo mi
Ọmọ Alhaji Tajudeen ọmọ Owóyẹmi
Aláṣẹ Avalon lọmọ Owóyẹmí
Aláṣẹ Radisson ọmọ Owóyẹmí
Èèyàn AB Motors ọmọ Agboọlá
Èèyàn Commander Àrẹ̀mú gangan Olúshọlá
Luxiria Construction Company tó ń talé
Àwọn làmìlaka l’Abuja
Luxiria Construction Company tó ń ta’lé)
(Àwọn làmìlaka l’Abuja)
Written by: Okunola Saheed
instagramSharePathic_arrow_out