Featured In

Credits

PERFORMING ARTISTS
King Dr. Saheed Osupa
King Dr. Saheed Osupa
Performer
Okunola Saheed
Okunola Saheed
Drums
COMPOSITION & LYRICS
Okunola Saheed
Okunola Saheed
Songwriter
PRODUCTION & ENGINEERING
Okunola Saheed
Okunola Saheed
Producer

Lyrics

Ayé, mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí
Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
(Mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí)
(Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo)
Àní sẹ́ mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí
Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
(Mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí)
(Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo)
Ọkùnrin tó lówó ìlú, kí ẹ wá fi’re wá mi rí
Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
(Mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí)
(Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo)
 Obìnrin ọlọ́lá ìlú, kí ẹ wá fi’re wá mi rí
Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
(Mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí)
(Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo)
Alágbára m’óṣèlú ìlú, kí ẹ wá fi’re wá mi rí
Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
(Mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí)
(Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo)
Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
Èmi àti ire pẹ̀kíǹrẹ̀kí láyé mi ni ká ṣe
Kí ire ayé mi má fò mí bẹ bá fire wá mi
Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
(Mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí)
(Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo)
Àní ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
Ìtàkùn àgbálùmọ́ ṣe ló ń toro mọ́ igi
Ire tọ̀tún tòsì láyé ń bí toro mọ mi
Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo
(Mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí)
(Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo)
Ìwo àgbò tímọ́tímọ́ mà ló ń mọ orí ire ayé mi
Tímọ́tímọ́ kó mọ́rí mi kalẹ́ ni
(Mo ti jí lèní, kí ẹ wá fi’re wá mi rí)
(Ìran àkàrà ní ń wá rere f’épo)
Láláìṣọkà, ìwọ̀n ni iyán ń gbóná mọ
Láláìṣọkà, ìwọ̀n ni iyán ń gbóná mọ
Láìsí lóko ẹrú, Ìyá ò le wá tọ́ sí mi
Láìsí lóko ẹrú, Ìyá ò le wá tọ́ sí mi
Láì dẹ̀ ṣẹ Ọlọ́hun, Ọba mi tó dá gbogbo wa
Láì dẹ̀ ṣẹ Ọlọ́hun, Ọba mi tó dá gbogbo wa
Ilẹ̀ gbọ́rọ̀ Olúwa,( kí n tẹ́lẹ̀ h’ewú gburugbu)
Ilẹ̀ gbọ́rọ̀ Olúwa, (kí n tẹ́lẹ̀ h’ewú gburugbu)
Ilẹ̀ gbọ́rọ̀ Olúwa, (kí n tẹ́lẹ̀ h’ewú gburugbu)
Lórí ìwọ ilẹ̀ (mo gbọdọ̀ máa lọ́lá rẹpẹtẹ)
Lórí ìwọ ilẹ̀ (mo gbọdọ̀ máa lọ́lá rẹpẹtẹ)
Bíbélì ló ní a pa Naboti
(Torí nǹkan ìní ẹ̀ ó)
(Ọkọ̀ Àjàrà ranjú mọ́ Ọba Mabu wo)
(Ọkọ̀ Àjàrà yìí ló fẹ́ f’ọgbọ́n gbà o)
(Ló fi bẹ Jésíbẹ́lì ní Samaria tó lọ pá)
Ó ń bẹ nínú Bíbélì o, òṣùpá
Bíbélì ló ní a pa Naboti
(Torí nǹkan ìní ẹ̀ ó)
(Ọkọ̀ Àjàrà ranjú mọ́ Ọba Mabu wo)
(Ọkọ̀ Àjàrà yìí ló fẹ́ f’ọgbọ́n gbà o)
(Ló fi bẹ Jésíbẹ́lì ní Samaria tó lọ pá)
L’ọlọ́hun bá ní ẹ fún wọn l’óko wọn
Ọtà àjàrà wọn, níjà ọgọ́rùn-ún
Oore Naboti tí wọ́n ti kó lọ tẹ́lẹ̀ ni
T’Ọ́lọ́run Ọba ní kí wọ́n dá padà tó pàṣẹ ni
Ògo tí wọn ò jẹ́ kí bàbá rí lò la fún ọmọ
(Gbogbo ogun Jésíbẹ́lì nínú ayé mi ò)
(Mo fi bú)
Àní Ọlọ́hun ló sọ bẹ́ẹ̀ o
Ọlọ́hun ló ní ẹ fún wọn lóko wọn
( Ọtà àjàrà wọn, níjà ọgọ́rùn-ún)
Oore Naboti tí wọ́n ti kó lọ tẹ́lẹ̀ ni
T’Ọ́lọ́run Ọba ní kí wọ́n dá padà tó pàṣẹ
Ògo tí wọn ò jẹ́ kí bàbá rí lò la fún ọmọ
(Gbogbo ogun Jésíbẹ́lì nínú ayé mi ò)
(Mo fi bú)
Ẹ gbọ́ kí ló kàn lọ́rọ̀ mi? (Òbítíbitì owó ni)
Kí n fowó máa dárà ṣe (nǹkan dáadáa si)
Àní kí ló kàn lọ́rọ̀ mi? (Òbítíbitì owó ni)
Kí n fowó máa dárà ṣe (nǹkan dáadáa si)
Ikú kọ́ ló kàn lọ́rọ̀ mi (èmi ọmọ ọjọ́ wo)
Àrùn kọ́ ló kàn lọ́rọ̀ mi (àfi ara líle)
Ò** kọ́ ló kàn lọ́rọ̀ mi (àf’ohun rere)
Kí n fowó máa dárà ṣe nǹkan dáadáa si
Ká ṣiṣẹ́ ò dàbí kí èèyàn r’érè jẹ (kó dé tún m’ówó délé)
Ká ṣiṣẹ́ ò dàbí kí èèyàn r’érè jẹ (kó dé tún m’ówó délé)
T’alubarika bá wọ iṣẹ́ ẹ̀dá (làgbà oore gidi)
T’alubarika bá wọ iṣẹ́ ẹ̀dá (làgbà oore gidi)
Àlùbáríkà tí ẹ̀ ń wò yẹn (kò kì ń dédé wọ iṣẹ́)
Àlùbáríkà tí ẹ̀ ń wò yẹn (kò kì ń dédé wọ iṣẹ́)
Èèyàn máa wa ni ò kéèyàn tó lè ri (ọ̀fẹ́ kọ́ ló bá dé)
Èèyàn máa wa ni ò kéèyàn tó lè ri (ọ̀fẹ́ kọ́ ló bá dé)
Owó iṣẹ́ tí mo kọ́ fọwọ́ mi gbà (mo ya ko fún màmá mi)
Owó iṣẹ́ tí mo kọ́ fọwọ́ mi gbà (mo ya ko fún màmá mi)
Màmá mi lówó yẹn n ó fi rà (àlùbáríkà fún mi)
Màmá mi lówó yẹn n ó fi rà (àlùbáríkà fún mi)
Àlùbáríkà tí màmá mi rà ( ni ìbùkún fi ń wọ iṣẹ́ mi)
Àlùbáríkà tí màmá mi rà ( ni ìbùkún fi ń wọ iṣẹ́ mi)
Lè ṣẹbọ, lè ṣòògùn (kò lè ju kádàrá lọ)
Lè ṣẹbọ, lè ṣòògùn (kò lè ju kádàrá lọ)
Bí ẹ̀dá ṣe wáyé pé ẹ̀dá máa dà (lẹ̀dá máa rí ará mi)
Bí ẹ̀dá ṣe wáyé pé ẹ̀dá ma dà (lẹ̀dá máa rí ará mi)
Ọba tó ṣ’òtútù ló ṣe ọyẹ́ pẹ̀lú oru
(Ọba tó ṣ’òtútù ló ṣ’ọyẹ́ pẹ̀lú oru)
Ọlọ́hun Ọba tó ṣ’òtútù ló ṣe ọyẹ́ pẹ̀lú oru
(Ọba tó ṣ’òtútù ló ṣ’ọyẹ́ pẹ̀lú oru)
Ó ṣe ọ̀sán, ó dẹ̀ ṣe òwúrọ̀, ó tún ṣe ìyálẹ̀ta m’álẹ́
(Ó ṣe ọ̀sán, ó dẹ̀ ṣe òwúrọ̀, ó tún ṣe ìyálẹ̀ta m’álẹ́)
Ó ṣe ọ̀sán, ó dẹ̀ ṣe òwúrọ̀, ó tún ṣe ìyálẹ̀ta m’álẹ́
(Ó ṣe ọ̀sán, ó dẹ̀ ṣe òwúrọ̀, ó tún ṣe ìyálẹ̀ta m’álẹ́)
Àbí ẹ rò pé nǹkan wà tí Waheedu ò le ṣe ni
(Àbí ẹ rò pé nǹkankan wà tí Waheedu ò le ṣe ni)
Àbí ẹ rò pé nǹkan wà tí Waheedu ò le ṣe ni
(Àbí ẹ rò pé nǹkankan wà tí Waheedu ò le ṣe ni)
Ọba tó ṣe fún oníwá tó ṣe fún ẹlẹ́yìn lỌba’re
(Ọba tó ṣe fún oníwá tó ṣe fún ẹlẹ́yìn lỌba’re)
Ọba tó ṣe fún oníwá tó ṣe t’ẹlẹ́yìn lỌba’re
(Ọba tó ṣe fún oníwá tó ṣe t’ẹlẹ́yìn lỌba’re)
Gbogbo ohun tó wu ẹ̀dá mà ló le b’Ọ́lọ́hun Ọba sọ
(Gbogbo ohun tó wu ẹ̀dá mà ló le b’Ọ́lọ́hun Ọba sọ)
Gbogbo ohun tó wu ẹ̀dá mà ló le b’Ọ́lọ́hun Ọba sọ o
(Gbogbo ohun tó wu ẹ̀dá mà ló le b’Ọ́lọ́hun Ọba sọ)
Ọba tó ń gbọ́ bùkátà, fún ogúnlọ́gọ̀ ẹ̀dá láyé
(Ọba tó ń gbọ́ bùkátà, fún ogúnlọ́gọ̀ ẹ̀dá láyé)
Ọba tó ń gbọ́ bùkátà, fún ogúnlọ́gọ̀ ẹ̀dá láyé o
(Ọba tó ń gbọ́ bùkátà, fún ogúnlọ́gọ̀ ẹ̀dá láyé)
Àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé kan ni gbogbo
Ọ̀dọ́ fẹ́ máa kú lọ rẹpẹtẹ
Àgbà Ìjẹ̀bú lọ sá tọ Ọ̀rúnmìlà
Nifá bá sọ pé Ìjàpá lẹbọ
(Àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé kan ni gbogbo)
(Ọ̀dọ́ fẹ́ máa kú lọ rẹpẹtẹ)
(Àgbà Ìjẹ̀bú lọ sá tọ Ọ̀rúnmìlà)
(Nifá bá sọ pé Ìjàpá lẹbọ)
Ìjẹ̀bú ra Ìjàpá, wọ́n ń sin ahun lọ
Ìjẹ̀bú ra Ìjàpá, wọ́n ń sin ahun lọ
Ìjẹ̀bú ra Ìjàpá, wọ́n ń sin ahun lọ
Ọ̀dọ́ ò kú mọ́ ara ń dẹ gbogbo wọn
Làwọn ìlú tó kú bá ń béèrè
Ọgbọ́n kí laláárẹ̀ dá gangan?
(Àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé kan ni gbogbo)
(Ọ̀dọ́ fẹ́ máa kú lọ rẹpẹtẹ)
(Àgbà Ìjẹ̀bú lọ sá tọ Ọ̀rúnmìlà)
(Nifá bá sọ pé Ìjàpá lẹbọ)
Ìgbà tí wọ́n wọ Ìjẹ̀bú tí wọ́n ń lọ tọpinpin
Ìgbà tí wọ́n wọ Ìjẹ̀bú tí wọ́n ń lọ tọpinpin
Ìjẹ̀bú fi inú han gbogbo wọn
Ìjẹ̀bú fi inú han gbogbo wọn
Wọ́n jẹ́ o yé wọn pé Ìjàpá lẹ̀rọ̀
Ni wọ́n fi ń sọ pé Ìjẹ̀bú lahun
(Àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé kan ni gbogbo)
(Ọ̀dọ́ fẹ́ máa kú lọ rẹpẹtẹ)
(Àgbà Ìjẹ̀bú lọ sá tọ Ọ̀rúnmìlà)
(Nifá bá sọ pé Ìjàpá lẹbọ)
Ìjẹ̀bú ìgbà yẹn wọ́n ń sin ahun ni
Ìjẹ̀bú ìgbà yẹn wọ́n ń sin ahun ni
Ẹranko abahùn lẹ́yìn bí ọnà
Ní wọ́n fi ń sọ pé Ìjẹ̀bú láhun
(Àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé kan ni gbogbo)
(Ọ̀dọ́ fẹ́ máa kú lọ rẹpẹtẹ)
(Àgbà Ìjẹ̀bú lọ sá tọ Ọ̀rúnmìlà)
(Nifá bá sọ pé Ìjàpá lẹbọ)
Ìjẹ̀bú ti gbọ́n jù wọ́n ti lóye jù wọ́n léte
(ibì kan jàjà ń bẹ ní Ìjẹ̀bú òde)
(Ìjà òsì ń bẹ níbẹ̀ ní’jẹ̀bú òde)
(Fìdípọ̀tẹ̀ lágbolé ibì kan mà ni)
(Ṣọ̀tẹ̀-márù lágbolé I ìkan tún ni)
Ìjẹ̀bú ti gbọ́n jù o, Ìjẹ̀bú ti gbọ́ jù wọ́n ti lóye jù wọ́n léte
(ibì kan jàjà ń bẹ ní Ìjẹ̀bú òde)
(Ìjà òsì ń bẹ níbẹ̀ ní’jẹ̀bú òde)
(Fìdípọ̀tẹ̀ lágbolé ibì kan mà ni)
(Ṣọ̀tẹ̀-márù lágbolé I ìkan tún ni)
Wọ́n á ní kéri rà, kóri má ràá
Àgbà Ìjẹ̀bú, wọ́n fi ń kọ́mọ lẹ́nà ni
Tí wọn ò bá lówó lọ́wọ́ tí àlejò kan bá dé o
Saheed, wọ́n á dọ́gbọ́n fi tan àlejò jẹ
Bó ṣe wà látijọ́ nìyẹn, Ìjẹ̀bú ó ti pẹ́
Wọ́n á ní kéri rà, kóri má ràá
Àgbà Ìjẹ̀bú, wọ́n fi ń kọ́mọ lẹ́nà ni
Tí wọn ò bá lówó lọ́wọ́ tí àlejò kan bá dé o
Saheed, wọ́n á dọ́gbọ́n fi tan àlejò jẹ
Ìbàdàn ò ní ṣọ̀rẹ́ àìránnilógun o no be lie
Ọmọ Olúyọ̀lé ṣá ni mí o walai talai
Gbogbo ọmọ Ìbàdàn akíkanjú ayé làwa
Ogun ò kó Ìbàdàn rí tipẹ́tipẹ́ nìyẹn
Afẹ́lẹ́ lẹ́nu á gbá ń nú orí gan kìkì ọpọlọ
A lè f’ọ̀rọ̀ ẹnu lásán tún’yàn ṣe
A tún lè f’ọ̀rọ̀ ẹnu faṣọ àpọ́nlé ya
Kò r’éṣù má lọ bá Ìbàdàn jagun ẹnu
Ìbàdàn nílé Olúyọ̀lé o
(Ìbàdàn ò ní ṣọ̀rẹ́ àìránnilógun o no be lie)
(Ọmọ Olúyọ̀lé ṣá ni mí o walai talai)
(Gbogbo ọmọ Ìbàdàn akíkanjú ayé làwa)
(Ogun ò kó Ìbàdàn rí tipẹ́tipẹ́ nìyẹn)
(Afẹ́lẹ́ lẹ́nu á gbá ń nú orí gan kìkì ọpọlọ)
(A lè f’ọ̀rọ̀ ẹnu lásán tún’yàn ṣe)
(A tún lè f’ọ̀rọ̀ ẹnu faṣọ àpọ́nlé ya)
(Kò r’éṣù má lọ bá Ìbàdàn jagun ẹnu)
Ìbàjẹ́ ọ̀rọ̀ lọ̀yọ́ ń y’ọ́mọ sílẹ̀ o
(Ọ̀yọ́ ń yọ̀ m’ónílé àti àlejò ni)
(Ọ̀yọ́ lọlá wà láti ayé àtijọ́ ni)
(Torí a sì gbà ni wọ́n sin Aláàfin Ọ̀yọ́ ilé o)
(Èèyàn tí ò bá ní ìwà tó da l’ọ̀yọ́ ń yọ́)
Àwọn ọmọ Ọ̀yọ́ gbajúmọ̀ gan
Ìbàjẹ́ ọ̀rọ̀ lọ̀yọ́ ń y’ọ́mọ sílẹ̀ o
(Ọ̀yọ́ ń yọ̀ m’ónílé àti àlejò ni)
(Ọ̀yọ́ lọlá wà láti ayé àtijọ́ ni)
(Torí a sì gbà ni wọ́n sin Aláàfin Ọ̀yọ́ ilé o)
(Èèyàn tí ò bá ní ìwà tó da l’ọ̀yọ́ ń yọ́)
Mesujanbi jana lọmọ Ìlọrin
(Ayé ló gbé Fathia síbi tí wọ́n gbé Kesruh sí)
(Wọ́n yí janbi wọ́n dẹ̀ sọ́ di ìjàǹbá)
(Janbi jana gan gan ló wá túmọ̀ sí)
(Ẹ̀gbẹ́ ibi tó súnmọ́ àlùjánà yẹn)
(Mesujanba tí wọ́n pe’lọrin o irọ́ ni)
Àpèǹpè ṣá lọ sọ janbi yẹn di janba irọ́
Mesujanbi jana lọmọ Ìlọrin
(Ayé ló gbé Fathia síbi tí wọ́n gbé Kesruh sí)
(Wọ́n yí janbi wọ́n dẹ̀ sọ́ di ìjàǹbá)
(Janbi jana gan gan ló wá túmọ̀ sí)
(Ẹ̀gbẹ́ ibi tó súnmọ́ àlùjánà yẹn)
(Mesujanba tí wọ́n pe’lọrin o irọ́ ni)
A jẹ oyè Máyégún Àwọ́tán kì í ṣe oyè kékeré
(Àwọn tó fún ẹ lóyè, wọ́n ri pé oyè yìí yẹ ẹ́)
(Torí ìwà èèyàn ni wọ̀n fi ń fún’yàn lóyè jẹ)
(Luku Àjàó ọkọ Islamia mi)
(Bàbá Mayowa bàbá Ọpẹ́yẹmí mà ni)
(Bàbá Zainab bàbá Halimotu Sadia)
(Máyégún Àwọ́tán tí Ìbàdàn ti bẹ̀rẹ̀ orísun)
Àjàó Lukumonu mi, Àjàó Máyégún Àwọ́tán kì í ṣe oyè kékeré
(Àwọn tó fún ẹ lóyè, wọ́n ri pé oyè yìí yẹ ẹ́)
(Torí ìwà èèyàn ni wọ̀n fi ń fún’yàn lóyè jẹ)
(Luku Àjàó ọkọ Islamia mi)
(Bàbá Mayowa bàbá Ọpẹ́yẹmí mà ni)
(Bàbá Zainab bàbá Halimotu Sadia)
(Máyégún Àwọ́tán tí Ìbàdàn ti bẹ̀rẹ̀ orísun)
Saheed Bakare Sidon Furniture tí ń gbòrò
(Ọkọ Muti Ọlọ́hun Ọba ti kàrámọ̀ ẹ)
(nídìí Furniture ó ti b’óde pàdé ó rówó o)
(Kó kàn ní branches kárí ayé o mà là ń retí)
Saheed Bakare o
Saheed Bakare Sidon Furniture tí ń gbòrò
(Ọkọ Muti Ọlọ́hun Ọba ti kàrámọ̀ ẹ)
(nídìí Furniture ó ti b’óde pàdé ó rówó o)
(Kó kàn ní branches kárí ayé o mà là ń retí)
Ayé ló sọ pé Òṣùpá o
Ayé ló sọ pé Òṣùpá borderless musician ni
(Mr Money agbára owó mi ní Gabon)
(Ọlọ́ládé ọkọ Ọlábísí là ń sọ)
(Àti àwọn kówópé cotonou kabiru mi)
(Béèyàn sọ Dear nu tó ṣe agent Àkànní)
(Èèyàn Ishola Raufu mo gbà fun)
(Wọ́n ní Òṣùpá orin Ọba wọ border gan)
(Benenois, Gabonese, saiphorians, Burkinabé pátá wọ́n fẹ́ràn orin Ọba)
Àwọn ayé ló sọ bẹ́ẹ̀ o
Ayé ló sọ pé Òṣùpá borderless musician ni
(Mr Money agbára owó mi ní Gabon)
(Ọlọ́ládé ọkọ Ọlábísí là ń sọ)
(Àti àwọn kówópé cotonou kabiru mi)
(Béèyàn sọ Dear nu tó ṣe agent Àkànní)
(Èèyàn Ishola Raufu mo gbà fun)
(Wọ́n ní Òṣùpá orin Ọba wọ border gan)
(Benenois, Gabonese, saiphorians, Burkinabé pátá wọ́n fẹ́ràn orin Ọba)
Ṣílé Alexander mi
Alexander Ṣílé onílẹ̀ ní Mòwé
(Èèyàn Ọọ̀nirìṣà l’olówó l’olóyè o)
(Bàbá Olóyè méjì pọ̀ ni Ṣílé)
(Ó jẹ àgbàakin ó dẹ̀ tún joyè Baṣọ̀run)
Ṣílé Alexander mi
Alexander Ṣílé onílẹ̀ ní Mòwé
(Èèyàn Ọọ̀nirìṣà l’olówó l’olóyè o)
(Bàbá Olóyè méjì pọ̀ ni Ṣílé)
(Ó jẹ àgbàakin ó dẹ̀ tún joyè Baṣọ̀run)
Abu mi Abel mi
Abu mi Abel Street Authority tó mọ rules
Ó ní to bá gbọpẹ́ ọmọ ọpẹ́ ko maintain steeze
To bá gbọpẹ́ ko kálá to kàn look away
Abu Ọba settlement lá padà mú ẹ sọ́wọ́ o
Bàbá èèyàn Abel Ẹgbárin
Abu mi Abel mi
Abu mi Abel Street Authority tó mọ rules
Ó ní to bá gbọpẹ́ ọmọ ọpẹ́ ko maintain steeze
To bá gbọpẹ́ ko kálá to kàn look away
Abu Ọba settlement lá padà mú ẹ sọ́wọ́ o
Bàbá èèyàn Abel Ẹgbárin
Saheed ìbílẹ̀ lẹni tí wọ́n gbèrò kó ṣubú
Tí kúrákútá wọn máa ń padà wá dòfo
Kí ní wọ́n fẹ́ bá Ọlọ́hun Ọba fà ju tesbiyu lọ
Ọmọ Fọláshadé ayaba mọ́là Audu mi
Bàbá Àrẹ̀mú ọkọ Adébímpé mi Àṣàkẹ́
Bàbá Ayélàágbé bàbá Bilikisu mi
Àfi tí múni múni ayé kan bá ti lè mú Ọlọ́hun
Saheed Ìbílẹ̀ á máa ja àjàyè ni
Saheed ìbílẹ̀ o, Àjàó
Saheed ìbílẹ̀ lẹni tí wọ́n gbèrò kó ṣubú
Tí kúrákútá wọn máa ń padà wá dòfo
Kí ní wọ́n fẹ́ bá Ọlọ́hun Ọba fà ju tesbiyu lọ
Ọmọ Fọláshadé ayaba mọ́là Audu mi
Bàbá Àrẹ̀mú ọkọ Adébímpé mi Àṣàkẹ́
Bàbá Ayélàágbé bàbá Bilikisu mi
Àfi tí múni múni ayé kan bá ti lè mú Ọlọ́hun
Saheed Ìbílẹ̀ á máa ja àjàyè ni
Àjàó bí wọ́n gbẹ́jọ́ wá
Ọlọ́hun ló l’àwíjàre, ẹni mọ Ọlọ́hun ṣá lọ̀gá mọ̀yàn mọ̀yàn
Èèyàn Wọlé Arisekola Abọ́dẹrìn ní Ìbàdàn
Èèyàn Gbadewọ̀lú Lukumonu Àjàó
Èèyàn Alágbàlá gangan awo Champion mi
Èèyàn elénìyàn tó jẹ Ààrẹ Surveyor mi
Èèyàn Kọ́lá Elépo o World K
Afi tí múni múni ayé kan bá ti lè mú Ọlọ́hun
Saheed Ìbílẹ̀ á máa ja àjàyè ni
Grandville lẹ fẹ́ ni, Harmony lẹ fẹ́ ni, Majestic lẹ fẹ́ ni
Paramount lẹ fẹ́ ni, Lekki Aviation 1,2,3 Farm City lẹ fẹ́ ni
Ọgbà ìdẹ̀ra o Citadel Estate bí i méje
(Grandville lẹ fẹ́ ni, Harmony lẹ fẹ́ ni, Majestic lẹ fẹ́ ni)
(Paramount lẹ fẹ́ ni, Lekki Aviation 1,2,3 Farm City lẹ fẹ́ NÍ)
(Ọgbà ìdẹ̀ra o Citadel Estate bí i méje)
Àní Grandville lẹ fẹ́ ni, Harmony lẹ fẹ́ ni, Majestic lẹ fẹ́ ni
Paramount lẹ fẹ́ ni, Lekki Aviation 1,2,3 Farm City lẹ fẹ́ ni
Ọgbà ìdẹ̀ra o Citadel Estate bi méje
(Grandville lẹ fẹ́ ni, Harmony lẹ fẹ́ ni, Majestic lẹ fẹ́ ni)
(Paramount lẹ fẹ́ ni, Lekki Aviation 1,2,3 Farm City lẹ fẹ́ NÍ)
(Ọgbà ìdẹ̀ra o Citadel Estate bí méje)
Written by: Okunola Saheed
instagramSharePathic_arrow_out