Featured In

Credits

PERFORMING ARTISTS
Sola Allyson
Sola Allyson
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Sola Allyson
Sola Allyson
Composer
PRODUCTION & ENGINEERING
Sola Allyson
Sola Allyson
Producer

Lyrics

[Verse 1]
Ọm'ọba o a rán mi sí ọ l'ẹ́ẹ̀kan si
Èyí l'ohun tí mo gbọ́ nígbà ìpòruru ọkàn tèmi
Mo dẹ̀ mọ̀ pé kìí ṣe fún èmi nìkan
Fún irú u mi fún àwa ọmọ, ọmọ ìmọ́lẹ̀
Láti mọ̀ n'írìn àjò yí o pé k'áa má gbàgbé o
Ohun tí mo gbọ́ nígbà ìpòruru ọkàn mi eyí ni pé k'áa má gbàgbé o
Ó ńkọ sí mi ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ọkàn mi lójúbọ ẹ̀mí i mi níbití mo ti máa ń gbọ́
Ó ní kí n má gbàgbé o
Ìrìn àjò máa ńrí bẹ́ẹ̀ n'ígbà mí b'áyé ti rí nìyẹn kò s'óhun t'áa lè ṣe si
Ṣùgbọ́n ọm'ọba má gbàgbé o
Ìrànwọ́ ń bọ̀, ìrànwọ́ ń bọ̀, ìrànwọ́ ń bọ̀, ìrànwọ́ ń bọ̀, ìrànwọ́ ń bọ̀ ọmọ
Ọm'ọba má gbàgbé o
[Verse 2]
Mo gbọ́ ohùn kan o
Mo gbọ́ ohùn kan nígbà ìpòruru ọkàn
Ìgbà tí mo ro gbogbo ìrìn yẹn o
Mo gbọ́ ohùn kan
Mo gbọ́ ohùn kan nígbà ìpòruru ọkàn
Ìgbà tí mo ro gbogbo ìyà yẹn o
Ó ń wí sí mi
Ó ń wí sí mi ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ọkàn
Pé kí n má gbàgbé ìràpadà mi
Ó ń kọ́ sí mi o
Ó ń kọ́ sí mi ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ọkàn
Lórísun ẹ̀mí ì mi
Pé kí n má gbàgbé ìràpadà mi
Mo gbọ́ ohùn kan o
Mo gbọ́ ohùn kan nígbà ìpòruru ọkàn
Ìgbà tí mo ro gbogbo ìrìn yẹn o
Mo gbọ́ ohùn kan
Mo gbọ́ ohùn kan nígbà ìpòruru ọkàn
Ìgbà tí mo ro gbogbo ìyà yẹn o
Ó ń wí sí mi
Ó ń wí sí mi ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ọkàn
Pé kí n má gbàgbé ìràpadà mi
Ó ń kọ́ sí mi o
Ó ń kọ́ sí mi ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ọkàn
Pé kí n má gbàgbé ìràpadà mi
[Chorus]
Ó ń wí pé
Ọm'ọba má mi'kàn, ọm'ọba má ṣ'ojo, ọm'ọba má gbàgbé o
Ọm'ọba má mi'kàn
Ọm'ọba má mi'kàn, ọm'ọba má ṣ'ojo, ọm'ọba má gbàgbé o
Ọm'ọba má mi'kàn
Ọmọ ìmọ́lẹ̀ má mi'kàn
Ó máa ń rí bẹ́ẹ̀ n'ígbà míì
Wàá m'ọ́nà rẹ pọ̀n ni
Wàá gb'ójú s'ókè, oò ní gb'ọ́kàn s'ókè, má mi'kàn
Gb'ójú s'ókè má gb'ọ́kàn s'ókè
Ọm'ọba má mi'kàn
Iṣẹ́ t'áa rán mi sí ọ nìyẹn
Èyí l'ohun tí mo gbọ́ nígbà a tèmi
Mo dẹ̀ mọ̀ pé kìí ṣe fún èmi nìkan
Fún irú ù mi bí ìwọ
Ọm'ọba má mi'kàn, ọm'ọba má ṣ'ojo, ọm'ọba má gbàgbé o
Bàbá rẹ ló ni l'ọ̀rọ̀
Bàbá rẹ ló l'ọ̀rọ̀, Bàbá rẹ ló l'oore gbogbo, Bàbá rẹ ló ni ògo
Bàbá rẹ ló ni l'ọ̀rọ̀
Bàbá ọl'ọ́rọ̀
Bàbá olóore
Bàbá ológo èmi ọmọ ológo
Èmi ọmọ ológo Bàbá ológo
Èmi ọmọ ológo
Èmi l'ọmọ Bàbá olóore
Èmi l'ọmọ Bàbá ológo
A ti rà ọ̀ padà
A ti rà ọ̀ padà, a ti ṣe ọ́ l'ọ́ọ̀ṣọ́, a ti mú ọ wọlé ìmọ́lẹ̀ s'íbi ààyè rẹ
O ti f'ọ́ṣọ́ ṣ'ayọ́, a ti sọ ọ́ d'ọmọ, ọm'ọba má gbàgbé o
A ti rà ọ̀ padà
A ti rà ọ̀ padà, a ti ṣe ọ́ l'ọ́ọ̀ṣọ́, a ti mú ọ wọlé ìmọ́lẹ̀ s'íbi ààyè rẹ
O ti f'ọ́ṣọ́ ṣ'ayọ́, a ti sọ ọ́ d'ọmọ, ọm'ọba má gbàgbé o
[Verse 3]
So that's our song, awa ọm'ọba
Àwa t'á ń r'ìrìn ìmọ́lẹ̀
Ó máa ń rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì
Ọkàn máà ń ṣ'àárẹ́ nígbà míì
Ṣùgbọ́n àá m'ọ́nà wa pọ̀n ni nínú ìmọ́lẹ̀
In the values of God
[Verse 4]
Ọm'ọba má mi'kàn, ọm'ọba má ṣ'ojo
Ẹ̀rù lè b'ọmọ Baba ṣùgbọ́n ibi ò lè ṣẹlẹ̀ s'ọ́mọ Baba nítorí Baba wà l'ẹ́hìn ọmọ Baba
Ọm'ọba má mi'kàn, ọm'ọba má ṣ'ojo, ọm'ọba má gbàgbé o
Èèyàn máa nfẹ́ gbàgbé nígbà mí nígbà ìpòruru ọkàn
Ìbéèrè máa ń pọ̀ nígbà míì
Ṣùgbọ́n m'ọ́nà rẹ pọ̀n nínú ìmọ́lẹ̀
Ṣiṣẹ́ ìmọ́lẹ̀, r'ìrìn ìmọ́lẹ̀, r'èrò ìmọ́lẹ̀, gb'áyé ìmọ́lẹ̀
Ìmọ́lẹ̀ á tàn, á máa tàn si láti orísun
Láti àgbàlá ìmọ́lẹ̀ kìí kú
Ìmọ́lẹ̀ ò ní kú f'ọ́mọ ìmọ́lẹ̀
Bàbá ológo á wà fún ọmọ ológo, ọmọ ológo á ṣ'ògo
B'ó ti wù k'ó rí ọmọ ológo, ọmọ ológo á ṣ'ògo
Nígbà t'ó jẹ́ pé Bàbá mi ló ni ògo
[Chorus]
Bàbá mi ló l'ọ̀rọ̀, Bàbá mi ló l'oore gbogbo, Bàbá mi ló ni ògo
Mo ti f'ọ̀ṣọ́ ṣ'ayọ̀, a ti sọ mí d'ọmọ, a ti mú mi wọlé ìmọ́lẹ̀ níbi ààyè mi
A ti rà mí padà mo ti di ọmọ
I am a child mi ò ní gbàgbé o
Ọm'ọba má gbàgbé o
[Verse 5]
I am a child mo d'ọmọ mo gbọ́ o, mo gbọ́
I am a child ọmọ l'èmi, mo gbọ́ o, mo ti gbọ́
I am a child of the Almighty, mo gbọ́ o, mo gbọ́
Ẹ̀mí mímọ́ sọ bẹ́ẹ̀ fún mi nígbà ìràpadà mi, mo gbọ́ o, mo ti gbọ́
Ọkàn mi gbọ́ má gbàgbé ìlérí ì yẹn
Whatever may come mo gbọ́
A ti rà mí padà, mo ti d'ọmọ, mo gbọ́ o, mo gbọ́ o
[Chorus]
Bàbá mi ló ni ọrọ̀, Bàbá mi ló l'oore gbogbo, Bàbá mi ló ni ògo
Ọm'ọba má mi'kàn
Ọm'ọba má mi'kàn, ọm'ọba má ṣ'ojo, ọm'ọba má gbàgbé o
Ìrìn àjò máà ń rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì
Àwa ò tiẹ̀ mọ'hun a bá ńlẹ̀
Má ṣ' ojo o
Níwọ̀n ìgbà t'óo bá ti t'ọ̀nà ìmọ́lẹ̀
Má mi'kàn
Wá wọlé sínú ilé ìmọ́lẹ̀, come, come
Wá wọlé o ọmọ, sílè ìmọ́lẹ̀, níbi ìmọ́lẹ̀, wá wọlé síbi ààyè rẹ
Bàbá rẹ ló ni ọ̀rọ̀
Bàbá rẹ ló l'ọ̀rọ̀, Bàbá rẹ ló l'oore gbogbo, Bàbá rẹ ló ni ògo
Àb'óò mọ̀ ni, ab'óò mọ ni
Àb'óò ti gbàgbé Bàbá à rẹ ni
Bàbá ìmọ́lẹ̀ olórísun ìmọ́lẹ̀, olórísun ohun gbogbo o
A ti rà ọ̀ padà
A ti rà ọ̀ padà, a ti ṣe ọ́ l'ọ́ṣọ́, a ti mú ọ wọlé ìmọ́lẹ̀ s'íbi ààyè rẹ
O ti f'ọ̀ṣọ́ ṣ'ayọ̀, a ti sọ ọ́ d' ọmọ, ọm'ọba má gbàgbé o
[Verse 6]
Ògo ìyìn ọla ló yẹ Ọlọ́run
Ọlọ́run àwọn'mọ ogun, Ọlọ́run àwọn'mọ ogun
Ògo ìyìn ọla ló yẹ Ọlọ́run
Ọlọ́run àwọn'mọ ogun, Ọlọ́run àwọn'mọ ogun
Ọba t'ó f'amọ̀ ṣ'olá
Ọba t' ó l'ẹ̀mí i wa
Ọlọ́run àwọn'mọ ogun, Ọlọ́run àwọn'mọ ogun
Ọba t'ó wà intentional
Ọba t'ó l'ẹ̀mí i wa
Ọba tí kìí ṣ'àṣìṣe Olúwa
Ọlọ́run àwọn'mọ ogun
[Verse 7]
K'ọ́lẹ̀ t'ó sọ nínú ìyá à mi l'o ti mọ̀ mí
Ọba t'ó l'ẹ̀mí ì mi
Oò dá mi fún'yà jẹ olúwa, Ọlọ́run àwọn'mọ ogun
Ojú ù mi k'ó là kí n m'ọ̀nà t'ó yẹ kí n gbà nínú ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀
Kí n wà nínú ìfẹ́ ẹ̀ rẹ
Ọlọ́run àwọn'mọ ogun, Ọlọ́run àwọn'mọ ogun
[Chorus]
Bàbá mi ló l'ọ̀rọ̀, Bàbá mi ló l'oore gbogbo, Bàbá mi ló ní ògo
Bàbá mi ló l'ọ̀rọ̀, Bàbá mi ló l'oore gbogbo, Bàbá mi ló ní ògo
Ṣé ọ̀rọ̀ ni mo fẹ́ ó wà ńbẹ̀
Ṣé oore ni mo fẹ́ ó wà ńbẹ̀
Ṣé ògo ni mo fẹ́ èmi ọmọ ológo
Bàbá mi ló ni ògo
Mà á r'ọ́rọ̀ lò, mà á r'íre lò, mà á r'ógo lò, mà á r'ọlá ṣe
Àṣèdalẹ́, àtànkálẹ̀, e bẹ́ẹ̀ ni
Bàbá mi ló l'ọ̀rọ̀, Bàbá mi ló l'oore gbogbo
Mi ò ní gbàgbé, ọm'ọba má gbàgbé o
Ọm'ọba má mi'kàn
Ọm'ọba má mi'kàn, ọm'ọba má ṣ'ojo, ọm'ọba má gbàgbé o
Ọm'ọba má mi'kàn
Whatever may come dúró, rọ́jú
Múra s'írìn rẹ
Ìmísí á wà ọm'ọba
Ọm'ọba má mi'kàn, ọm'ọba má ṣ'ojo, ọm'ọba má gbàgbé o
Written by: Sola Allyson
instagramSharePathic_arrow_out