Lyrics
[Intro]
Ebenezeri wa re o nibi tẹ ran wa lọwọ de
Ka maa jo, ka yọ, ka fogo f'Olu
[Verse 1]
Ninu irinkerido mi laye, hmm, Iwọ lo ba mi ṣe
Alubarika ti mo riri, emi kọ, iṣẹ Ọlọrun ni
Ewu gbogbo ti mo la kọja, ki ma i ṣagbara mi
Atinuda, ti mo ni lo jẹ ki n dupẹ oore
[Chorus]
Ebenezeri wa re o nibi tẹ ran wa lọwọ de (Nibi tẹ ran wa lọwọ de)
Ka maa jo, ka yọ, ka fogo f'Olu
(Ebenezeri) Ebenezeri wa re ẹ ma ma ṣe (ẹ ma ma ṣe ẹ ṣe)
Ki ma i ṣe nipa agbara, Oluwa lo ni imọ at'oye (Oluwa lo ni iranwọ lọwọ)
Ogo t'aye ri t'ọn polongo, Irẹ lo ba wa ṣe (Ogo t'aye ri t'ọn polongo, Irẹ lo ba wa ṣe)
Orin Halleluya, Hosana lo gbẹnu wa kan
[Verse 2]
O ba jọ, Ẹ ṣe, ibi tẹ ti bẹrẹ
Ẹ ṣe, ibi tẹ ba a de
A dupẹ Oluwa, ibi tẹ mu wa lọ
Tori i ba ṣe p'Oluwa, ko ti wa ni t'iwa o
Eh, eh nibo la ba ja si o? Amọ nisẹyin a dupẹ a tọpẹ da
Tori wi pe, awọn kan gbẹkẹle kẹkẹ awọn kan gbẹkẹle ẹṣin
Awa ta gbẹkẹle ọ, ibi to mu wa de re, ibi ogo ni, la ṣe wi pe
Orin Haleluyah, orin Hosana o, orin Ebenezer, Hosana lo gbẹnu wa kan
Ẹ kọrin Ebenezeri oh
[Chorus]
Ebenezeri wa re o nibi tẹ ran wa lọwọ de (Nibi tẹ ran wa lọwọ de) A ti de'bẹ
Ka maa jo, ka yọ, ka fogo f'Olu (Ka maa jo fayọ)
Ẹ ṣe ibi tẹ ti bẹrẹ
Ebenezeri wa re ẹ ma ma ṣe (Ibi tẹ ba wa de)
Ki ma i ṣe nipa agbara, Oluwa lo ni imọ at'oye (Oluwa lo ni iranwọ lọwọ)
Ogo t'aye ri t'ọn polongo, Irẹ lo ba wa ṣe (Ogo t'aye ri t'ọn polongo, Irẹ lo ba wa ṣe)
Orin Halleluya, Hosana lo gbẹnu wa kan
[Verse 3]
Oh oh oh
Oh oh oh
A panupọ a dupẹ (A dupẹ a yin ọ)
Oh oh oh
A kọrin ayọ a mọpẹ wa
Oh oh oh
Oh oh oh
A panupọ a dupẹ
Oh oh oh
A kọrin ayọ a mọpẹ wa
Tori pe (Agbọn-i-gbẹ ibukun aidiyele, to fi fun wa, la ṣe n dupẹ) Ẹ ho iho ayọ si Oluwa
[Verse 4]
oh oh oh
A panupọ a dupẹ
oh oh oh
A kọrin ayọ a mọpẹ wa
Ọkan mi yi Oluwa logo
oh oh oh
Mo fẹrẹ wa sọdọ rẹ
A panupọ a dupẹ
Adupẹ oh oh ho
oh oh oh
A kọrin ayọ a mọpẹ wa tori abuubutan oore rẹ
Agbọn-i-gbẹ ibukun aidiyele, to fi fun wa, la ṣe n dupẹ
Tori agbọn-i-gbẹ ibukun aidiyele, to fi fun wa, la ṣe n dupẹ
Gbogbo aye ni sọrọ logo rẹ tori abuubutan oore to ṣe fun mi (La ṣe n dupẹ)
[Outro]
Ebenezeri wa re o nibi tẹ ran wa lọwọ de
Ka maa jo, ka yọ, ka fogo f'Olu
(Ebenezeri) Ebenezeri wa, ẹ ma ma ṣe (Ẹ ṣe, ẹ ṣe)
Ki ma i ṣe nipa agbara, Oluwa lo ni imọ at'oye
Tori wi pe ogo t'aye ri t'ọn polongo, Irẹ lo ba wa ṣe
Orin Halleluya, Hosana lo gbẹnu wa kan
Written by: Kent Edunjobi