Similar Songs
Credits
PERFORMING ARTISTS
Qdot
Performer
Qudus Fakoya
Lead Vocals
COMPOSITION & LYRICS
Dj Global
Composer
Qudus Fakoya
Lyrics
PRODUCTION & ENGINEERING
Gzik Tigermix
Producer
Lyrics
[Chorus]
Ẹ ṣamin o (Amin)
Wọn lọbọ kọ ko ṣamin (Amin)
Ti n ba ṣadura kẹ ṣamin o (Amin)
Aisan ma wọle (Amin)
Ibanujẹ ma wọle (Amin)
Owo ni ko wọle (Amin)
Ka ti ẹ ri visa japa (Amin)
Ki economy to pa wa (Amin)
Ọlọrun gba adura wa (Amin)
Kaṣọ iyi wa ma faya (Amin)
Kọmọ araye ma ṣe dan mi wo (Amin)
K'ọn ma fẹgba fun mi lounjẹ o (Amin)
Iya o gbọdọ jẹ mi (Amin)
Oṣi o gbọdọ ta mi (Amin)
A o ni ri ija aye (Amin)
Aye o ma ni ba wa ja (Amin)
Ko dun, ko po, ko pẹ (Amin)
Ma ṣe mi lolowo ana (Amin)
Ma jẹ n rogun agbana (Amin)
[Verse 1]
Mo fẹ pa bukata (Amin)
Bukata o gbọdọ pa mi (Amin)
Ẹfọn to jẹ baba mi (Amin)
E ma gbọdọ jẹ mi (Amin)
Ma ṣe mi ni almanjiri (Amin)
Talaka alagidi (Amin)
Kabu kabu ma ti su mi (Amin)
Emi naa fẹ ra mọto (Amin)
Imọ ọta o gbọdọ ṣẹ, ko gbọdọ ṣẹ, ko gbọdọ ṣẹ
Ẹnu mi o gbọdọ gbẹ, ko gbọdọ gbẹ, ko gbọdọ gbẹ
Tẹtẹ mi o gbọdọ jẹ, o gbọdọ jẹ, o gbọdọ jẹ
Ma jẹ n wa bakan naa mọ, emi naa fẹ ma tanna
[Verse 2]
Ma jẹ kaye pa imọlẹ mi (Amin)
Alubarika (Amin)
Alaafia (Amin)
Mo wolẹ mo n gbadura (Amin)
Onimajẹmu gbadura mi (Amin)
O lo ma ya mi lẹnu (Amin)
Ma jẹ n ba wọn ganu (Amin)
Ki n to rọwọ mu lọ sẹnu (Amin)
K'omi ma tan lamu (Amin)
Ma jẹ n ba wọn damu (Amin)
Ki n ma ṣaṣedanu (Amin)
[Verse 3]
Aṣiri a bo (Amin)
Ma ra 'Lambo (Amin)
Ọta maa ri mi yago (Amin)
Baba ma jẹ k'ọn pẹgan (Amin)
Ma jẹ kaye pe mi lagan (Amin)
Tori ko ṣẹ, ko ṣẹ ni ti'lakọṣẹ (Amin)
Ileri Ọlọhun gbọdọ ṣẹ (Amin)
Wọla ọjọ tiya n rọbi (Amin)
Ọlọrun wọla Yah Robbi (Amin)
Ma jẹ n waye lasan (Amin)
Ma jẹ n waye pasan (Amin)
Ma jẹ n waye wa jẹ pasan (Amin)
Ma jẹ n fiya ṣe ounjẹ ọsan (Amin)
Ṣe mi lolowo bi Dende (Amin)
Ọlọrun ṣaanu mi (Amin)
Bo ṣe ṣe iyanu fun Peller (Amin)
Billion dollar (Amin)
Orin gbọdọ dọla (Amin)
Talaka a di baller (Amin)
[Chorus]
Wọn lọbọ kọ ko ṣamin (Amin)
Ti n ba ṣadura kẹ ṣamin o (Amin)
Aisan ma wọle (Amin)
Ibanujẹ ma wọle (Amin)
Owo ni ko wọle (Amin)
Ka ti ẹ ri visa japa (Amin)
Ki economy to pa wa
Ọlọrun gba adura wa
Kasọ iyi wa ma faya
Kọmọ araye ma ṣe dan mi wo
K'ọn ma fẹgba fun mi lounjẹ o
Iya o gbọdọ jẹ mi
Oṣi o gbọdọ ta mi
Written by: Dj Global, Qudus Fakoya