Top Songs By Db Comic
Similar Songs
Credits
PERFORMING ARTISTS
Db Comic
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Bada Damilola
Songwriter
Lyrics
[Chorus]
Oluwa a ma riṣẹ yin o
Oluwa a ma rọwọ yin o
Awọn to ti gan wa tun wa n fọla wa tọrọ
Oluwa oh, a ma riṣẹ yin o
Oluwa a ma rọwọ yin o
Awọn to ti gan wa tun wa n fọla wa tọrọ
Gbogbo awọn taa ti ranlọwọ t'ọn ṣebi Ọlọrun ko wa tan bi
Awọn to ti gan wa tun wa n fọla wa tọrọ
[Verse 1]
Mo dupẹ mi o mu un bọ, mi o mu un bọ, mi o mu un bọ oh
Tori amubọ lọta n pinnu fun mi ehn
Ṣeni wọn n reti bi ki n wo, ki n ṣubu ninu irin-ajo yii o ọkọ mi
Koto t'awọn people yin dẹ silẹ mi o ko si i Baba mi
Wo ibi O faanu mu mi de
Bawo la ṣe debi yii naa o ọkọ mi?
Awọn to jẹ ọlọla t'ọn fọla jẹyan
Wọn tun wa n jowu ohun ti mo ni
Ko ru mi loju
Mo m'ẹni to ṣaanu mi, iwọ ni, Ọlọrun awọn baba wa
A ṣe wi pe olofo eniyan le pada di ologo eniyan, kai
Igbedide ti mo ri, ọwọ rẹ ni
Ọla ti mo ri, ọwọ rẹ ni ọkọ mi
Ogo to buyọ lara mi t'awọn eeyan yii n fi n pe mi lologo
Ọwọ rẹ ni, ọwọ rẹ ni, ọwọ rẹ ni ah
O ṣaanu de bi wi pe
[Verse 2]
Awọn to ti gan mi tun wa n fọla mi tọrọ
Mogaji awọn alagbara
Iwọ lo ba mi ṣe
Awọn to ti figba kan pe mi loloofo eniyan ri
Wọn fọla mi tọrọ
Alatilẹyin mi iwọ lo mu mi debi, ogo fun orukọ yin
Awọn to ti gan wa
Wọn ti lero pe nnkan ire o le taye awa eeyan yii jade
Awọn to ti figba kan ṣe ṣiọ si wa o
Wọn fọla wa tọrọ
Ọkọ mi, Baba mi iwọ lo ran wa lọwọ de'bi ta a de yii o
[Chorus]
Oluwa a ma riṣẹ yin o
Oluwa a ma rọwọ yin o
Awọn to ti gan wa tun wa n fọla wa tọrọ
[Verse 3]
O ma ma ṣe Eledumare
Mo ma ma dupẹ dupẹ alatilẹyin
A ni bi ki i ba ṣe ifẹ rẹ o, o, ki ni iba maa wi?
Ni tori wi pe
[Outro]
Awọn to ti gan wa tun wa n fọla wa tọrọ
Awọn to ti gan wa tun wa n fọla wa tọrọ
Awọn to ti gan wa o
Awọn to ti ro mi pin o
Awọn to ti ro mi pin wọn fọla emi tọrọ
Awọn to ti gan wa tun wa n fọla wa tọrọ
Iru emi yii
Awọn to ti gan wa tun wa n fọla wa tọrọ
Iru emi o
Ẹ ṣe o
Written by: Bada Damilola