Credits
PERFORMING ARTISTS
Sola Allyson
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Sola Allyson
Songwriter
Lyrics
Mo juba Oba
Mo juba Oba
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atererekariaye Olorun Awon Omo Ogun
Mo juba (mo juba Oba)
Mo juba re (mo juba Oba) Ólórun agbaye Iwoni Oba
Mo juba re oo (mo juba Oba) kosi elomi leyin re, Iwo nikan ni Oba
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atererekariaye Olorun awon omo ogun
Mo juba (mo juba Oba)
Iba Eledumare, Oba to ni gbogbo aye
Eni nla ti mbe lori ite titi lai, lai, lai
Emi mi b'ola fun O, o, lati ogbun iseda mi
Mo yi ka otun, mo yi t'osi, mo ba ruburubu
F'eni naa, alaponlejulo, eni ayeraye
Iwo lo ti mbe, Iwo loo si ma be
Leyin Re, ko si mo, Oba titi lai
Mo sin O, mo sin O, mo sin O, mo sin O
Lat'ogbun emi mi
Eni naa, Oba naa, oluwosan, alaanu
Gbogbo iseda ati emi, a n b'ola fun O
Mo juba (mo juba Oba) mo juba re oo
Gbogbo ohun towa ninumi juba (mo juba Oba) Oluwa, Olorun alaanu, mo juba re
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atererekariaye Olorun Awon Omo Ogun
Mo juba (mo juba Oba)
Iwo ni Oba ti o le pa'poda lailai
Oba to ti wa ti o si ma be tititi
Aye mi yio ma fi ibukun fun oruko Re
Ileke ola, Ipile oye, opin gbogbo ola
Gbogbo ise Re ni o ma yin O, a n pe O l'Oba
Iwo ni alaanu to f'ebun se mi loso
O tun fi ogo de ebun to fun mi lade
Odo Re naa ni gbogbo ogo naa n pada si Oluwa
Eni naa, Oba naa, oluwosan, alaanu
Gbogbo iseda ati emi, a n b'ola fun O
Gbogbo ise Re ati emi o (a n b'ola fun O)
Awon ohun taa ri at'awon ta o ri, won n b'ola fun O (a n b'ola fun O)
Loke orun lohun, lagbedemeji ile t'a n te, ogo ni f'ooko Re (a n b'ola fun O)
Iwo ni oni ike to po, Olola to po, Alaanu to po (a n b'ola fun O)
Ko si ede naa ni gbogbo aye ti iro ogo Re kii buyo Oluwa (a n b'ola fun O)
Hiho okun n bu ola fun O, Osa naa n b'ola fun O, gbogbo ise (a n b'ola fun O)
Gbogbo ede, gbogbo ijoba, lo n wariri fun oruko Re (a n b'ola fun O)
Gbogbo ise Re ati emi (a n b'ola fun O)
Written by: Sola Allyson, Tobi Aluko