Top Songs By Gbenga felefelelaye
Similar Songs
Credits
PERFORMING ARTISTS
Gbenga felefelelaye
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Gbenga felefelelaye
Songwriter
Lyrics
[Chorus]
Fẹlẹfẹlẹ laye, ile aye yi fẹlẹ o
Fẹlẹfẹlẹ laye gba o, ile aye yi fẹlẹ o
[Verse 1]
Ile aye le (Fẹlẹ laye)
Ogun nile aye (Fẹlẹ laye)
Ẹyinkule lọta wa (Fẹlẹ laye)
Ile laseni ngbe (Fẹlẹ laye)
Ọmọ iya n para wọn (Fẹlẹ laye)
Nitori ogun (Fẹlẹ laye)
Ọkọ n faya ṣẹso (Fẹlẹ laye)
Nitori ọla (Fẹlẹ laye)
Iyawo fọkọ wowo (Fẹlẹ laye)
Ọmọ fiya gunṣẹ (Fẹlẹ laye)
Nitori ọla (Fẹlẹ laye)
Ọrẹ n tan ọrẹ pa (Fẹlẹ laye)
Nitori owo (Fẹlẹ laye)
Aye le ọrẹ mi (Fẹlẹ laye)
Alagbara aye ẹ rọra (Fẹlẹ laye)
Ẹni a ni ko kinilẹyin (Fẹlẹ laye)
Ẹgun lo fi sọwọ (Fẹlẹ laye)
Ẹ ma m gbara leniyan (Fẹlẹ laye)
Ẹ sinmi le Ọlọrun (Fẹlẹ laye)
Ọlọrun to da a yin (Fẹlẹ laye)
Ẹ jẹ ka ṣe pẹlẹ o (Fẹlẹ laye)
Ẹ jẹ ka rọra laye (Fẹlẹ laye)
Alagbara aye ẹ rọra (Fẹlẹ laye)
Ko sohun ta ma mu lọ sọrun (Fẹlẹ laye)
Ronu rẹ ọrẹ mi (Fẹlẹ laye)
Ohun to ba n ṣe (Fẹlẹ laye)
Rikiṣi o da ọrẹ mi (Fẹlẹ laye)
Ọtẹ n dawo mọlẹ (Fẹlẹ laye)
Ohun to ba gbin lo maa ka (Fẹlẹ laye)
Ọrẹ mi ma gbin igi oro (Fẹlẹ laye)
Eeyan mi ma gbin igi ika (Fẹlẹ laye)
Ika a pa onika o (Fẹlẹ laye)
Ibi a gbẹyin aṣebi (Fẹlẹ laye)
Ọrẹ mi ika o sunwọn (Fẹlẹ laye)
Ẹ ṣe rere laye (Fẹlẹ laye)
Bi a ba sọ ọrẹ mi (Fẹlẹ laye)
Ayọ n bọ lowurọ (Fẹlẹ laye)
Iwa rere lẹṣọ eniyan (Fẹlẹ laye)
Gbele aye ṣe rere (Fẹlẹ laye)
Ẹbẹ ni ka bẹ olu ọrun (Fẹlẹ laye)
Ko gbawa lọwọ ẹni bi (Fẹlẹ laye)
Aṣebi abanidaro (Fẹlẹ laye)
Aye kan ṣoṣo lo wa (Fẹlẹ laye)
Tẹmi ba ja o tan niyẹn (Fẹlẹ laye)
Ma gbagbe ọmọ araye (Fẹlẹ laye)
A o meri ijọba (Fẹlẹ laye)
Ẹwẹku ẹwẹlu ẹwẹlẹ (Fẹlẹ laye)
Wọn fẹ ọ loju (Fẹlẹ laye)
Wọn ṣe ika ẹ lẹyin (Fẹlẹ laye)
Ẹwẹku ẹwẹlu ẹwẹlẹ (Fẹlẹ laye)
Aye le ọrẹ mi (Fẹlẹ laye)
Ifẹ ta ni sadiyẹ (Fẹlẹ laye)
Koju ka pa a jẹ (Fẹlẹ laye)
Aye le ọrẹ mi (Fẹlẹ laye)
Igba pẹlẹ ki i fọ (Fẹlẹ laye)
Awo pẹlẹ ki i ya (Fẹlẹ laye)
Eeyan o fẹnifọrọ (Fẹlẹ laye)
Bi aparo lọmọ araye n fẹ (Fẹlẹ laye)
Wọn o fẹ lekeleke o (Fẹlẹ laye)
Lekeleke alaṣọ funfun (Fẹlẹ laye)
Aṣegbe kan o ma si (Fẹlẹ laye)
Aṣepamọ lo n bẹ (Fẹlẹ laye)
A o ni gbiṣu ka kala (Fẹlẹ laye)
A o ni gbin ẹpa ka kaṣu (Fẹlẹ laye)
Rere lo pe ika o da (Fẹlẹ laye)
Gbele aye ṣe rere (Fẹlẹ laye)
Ka le kare bo dọla (Fẹlẹ laye)
Baye n fẹ ọ lọ ṣọra (Fẹlẹ laye)
Ohun taye sọ pe o gun (Fẹlẹ laye)
Wọn tun ni ko gun mọ o (Fẹlẹ laye)
Ma ṣe ruka galegale (Fẹlẹ laye)
Aye le ọrẹ mi (Fẹlẹ laye)
Ire owo, ire ọmọ (Fẹlẹ laye)
Aiku baalẹ ọrọ (Fẹlẹ laye)
Fẹyin ololufẹ wa (Fẹlẹ laye)
Tẹ ba faye lafaju (Fẹlẹ laye)
Aja mọ yin lọwọ
[Verse 2]
Bo ba jere lo mọ-ọn ṣe, yara maa ṣe lọ
Bo ba jẹ ika lo mọ-ọn ṣe, yara maa ṣe lọ
Fẹlẹfẹlẹ o laye yii gba o
[Chorus]
Fẹlẹfẹlẹ laye, ile aye yii fẹlẹ o
Fẹlẹfẹlẹ laye gba o, ile aye yii fẹlẹ o
Fẹlẹfẹlẹ laye, ile aye yii fẹlẹ o
Fẹlẹfẹlẹ laye gba o, ile aye yii fẹlẹ o
Written by: Gbenga felefelelaye