Similar Songs
Credits
PERFORMING ARTISTS
K1 De Ultimate
Performer
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Vocals
Babatope Joseph Temidayo
Drums
COMPOSITION & LYRICS
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Songwriter
Babatope Joseph Temidayo
Composer
PRODUCTION & ENGINEERING
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Executive Producer
Babatope Joseph Temidayo
Producer
Prince Oladeji Sunday Adele
Mixing Engineer
Iredumare Opeyemi
Executive Producer
Lyrics
Èrò tí ń r’òjéje e bá mi ki màmá mi
(Ẹ kí màmá mi fún mi o)
Èrò tí ń r’òjéje ẹ bá mi kí màmá mi
(Ẹ kí màmá mi fún mi o)
Èrò tí ń r’òjéje ẹ bá mi kí màmá mi
(Ẹ kí màmá mi fún mi o)
Mò ń ṣe é ó kò
Ẹ ẹ̀ r’áyé ọmọ tí ò ní màmá
Arábámbí Ọba orin o
Ìyá mi Alimotu Sadia ọmọ Moriamo Alégẹ
Ọmọ Kábíèsí Akérédolú nílùú Ìlúpéjú Èkìtì
Sùn-un re bo bá ti d’ọ́run Àbíkẹ́
Bí eré bí eré
Wọ́n ní bí ewé bá jábọ́ lára igi ó di gbéré
Ọmọ ò rí màmá ẹ̀ mọ́ arábámbí ó ṣe
Ọmọ Ọba nílùú Ìlúpéjú l’Èkìtì
Aya ọmọ Ọba Musa
Musa Kálámù mi Àdìsá
Adésànyà nílùú Ìjẹ̀bú Òde
Fìdípọ̀tẹ̀mọ́lẹ̀ Ojúṣàágbọlá mi ọ̀gọ́jì Àdìsá
Gbogbo syé ni mo dúpẹ́ fún
Láti orí President of the Federal Republic ìlú wa Nigeria
His Excellency President Bọ́lá Ahmed mi ọmọ Tinubú
Àkànbí olódó idẹ
Baàmi ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Ọkọ first lady Olúrẹ̀mí aya bàbá mi
Ọmọ òkúṣebíàlá nílùú Ìjẹ̀bú Òde
His Excellency ọmọ Ọba Dàpọ̀ Abíọ́dún
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògun State tiwa o pẹ̀lú Deputy Governor
Engineer Naimo Sàlàkọ́ aya ọmọ Ọba Oyèdélé
Fìdípọ̀tẹ̀ nílùú Ìjẹ̀bú Òde
Mo dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́
His Excellency Governor Babájídé Olúṣọlá ọmọ Sanwóolú
Ọkọ Dr Ìbíjọkẹ́ ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Pẹ̀lú Deputy Governor Dr Ọbáfẹ́mi Hamzat mi
Muhammad Quadri ọkọ Rẹ̀mí mo dúpẹ́ dúpẹ́
Ọpẹ́ mi pàtàkì pátákí lọ́wọ́ òrìṣà Ìjẹ̀bú
Bàbá mi Kábíèsí Ọba Adétọ̀nà Awùjalẹ̀ gbogbo Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú
Àwọn ni wọ́n direct Chief Imam Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú
Kí wọ́n lọ ṣí Central Mosque láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn
Fún màmá olórí ọmọ Ọba
Gbogbo league of Imams pátápátá ni mo dúpẹ́ fún
Láti orí bàbá wa Chief Imam ti Ìjẹ̀bú land
His Eminent Sheik Muftaudeen Gbádégẹṣin o
Ọmọ Àyánbádéjọ pẹ̀lú bàbá mi
His Eminence Imam SAN Bángbọ́lá
Chief Imam gbogbo Ẹ̀gbá land àti Mufti àgbà nílùú Ìlọrin o
His Eminence Sheikh Suleiman Faruk Oníkíjìpá
Ọkọ Seidat Ramotalahi mo dúpẹ́ dúpẹ́
Àti bàbá Adinni mi Ògùn state ni Débáyọ̀ Apẹ́lógun
All rounder mo dúpẹ́ dúpẹ́
Ọpẹ́ mi pàtàkì pàtàkì lọ́wọ́ my musical grandfather
Bàbá mi Evangelist Ebenezer Àrẹ̀mú Fábìyí Òbé
Bàbá àgbà pátápátá fún gbogbo Nigerian Musician
Mo dúpẹ́ mo dúpẹ́ ẹ ṣeun ṣeun
Lórúkọ gbogbo ẹgbẹ́ olórin pátápátá ní Nigeria
Àti gbogbo ẹgbẹ́ onílù mo dúpẹ́ dúpẹ́
Àrẹ̀mú Commander olórí gbogbo wa
Ẹ kú àdúrótì mo mọ̀ ọ́ lóore
Gbogbo wa la ma gbẹ̀yìn arúgbó wa o ni ti dáadáa
Murphy Adékọ̀yà Ọ̀gbẹ́ni ọjà ìlú àgọ́ ìwòye mo dúpẹ́
Èrò tí ń r’òjéje e bá mi ki màmá mi
(Ẹ kí màmá mi fún mi o)
Èrò tí ń r’òjéje e bá mi ki màmá mi
(Ẹ kí màmá mi fún mi o)
Láti National Assembly Senate pẹ̀lú House of Representatives
Distinguished Senator Ọ̀tunba Gbénga Daniel mi odidi ọmọ
Balógun bọ́bakẹ́yẹ Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú o
Mo dúpẹ́ dúpẹ́ mo t’ọ́pẹ́ dá
Senator Ọlámilékan Adéọlá yáyì ni jọ̀ọ́
Ọmọ West Yáyì ni jàre
Ẹ mà kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Senator Shuad Afọlábí mi Salisu
Senator Satiramoni ọmọ Musitapha ọ̀rẹ́ mi
Ọkọ ìyábọ̀sọ́lá Senator Dìrù tí ń jẹ́ Tòkunbọ̀
Ìkòròdú ọ̀gá ọmọ òriwù mo dúpẹ́ dúpẹ́
Senator Sanni Wasiu ọmọ ẹṣinlokùn
Senator Ìṣọ̀lá Musiliu Ọbaníkòró ọ̀rẹ́ mi ọmọ Olúwo ńlá
Senator Saliu Mustapha o
Senator Sharafadeen mi Allli
Ọkọ Alhaja Tawakalitu ọmọ Nalado Alausa
Honourable Babájìnmí Benson ọmọ ẹ̀lúkú mẹdẹ́ mẹdẹ́
Honourable Skime mo kí ẹ
Al Akeem ọmọ Ọláyíwọlá Adéyẹmí kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Honourable Démọ̀ọ́rìn mi Kúyẹ̀
Ọ̀túnba Àjànà of Ìjẹ̀bú Land ọkọ Sukaina
Honourable Túnjí Raimi ọmọ sọ’gbódilé ọmọ sọ̀’gbẹ́dìgboro
S’àkìtàn d’ọjà, àjùlọ ò pin nílé bàbá ẹ
Aṣojú ọmọ òmù àrán kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Honourable Yẹmí Alli owó ọkọ Yẹ́nsí
Rt Honourable Ọbasá mi Muda mi
Honourable Desmond Elliot mi
Gbogbo alága pátápátá mo dúpẹ́ dúpẹ́
Láti orí Chairman Conference 57
Honourable David Kọ́ládé Àlàbí ẹ kú àdúrótì
Pẹ̀lú Secretary Conference 57 lórúkọ gbogbo ilé
Honourable Razak mi Àjàlá àti ẹbí ẹ
Ayọ̀ọlá Fatai mi ẹ kú àdúrótì
Lórúkọ gbogbo ilé Àrẹ̀mú Adébáyọ̀ ọmọ Ọláṣojú
Mi ò le gbàgbé Honourable Minister for Power
Débáyọ̀ Adégòkè Pẹnkẹlẹ pẹ̀lú Distinguished Senator
Àjírí ọmọ oyè Senator Ìbíkúnlé ọmọ Amósùn
Mo dúpẹ́ dúpẹ́ mo mọ̀ ọ́ lóore
Ambassador Sharagadeen mi Túnjí ọmọ Ìṣọ̀lá
Ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Honourable Gbóyèga Nasir ọmọ Isiaka awo tèmi arábámbí
Honourable Mikky Kazeem mi
Honourable Rótìmí ọmọ ti Àjànàkú
Dino ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Prince Adéṣẹ́gun Onírù awo tèmi Àyìndé mọ́gbọ́láhàn
Àti Àlàbí Akínṣìkù ọkọ Naimo
Gbogbo Ọba ládé ládé mo dúpẹ́ dúpẹ́
Ẹ kú àdúrótì mo mọ̀ ọ́ lóore
Lórúkọ gbogbo ọba ní Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú
Èbúmàwé àgọ́
Orímolúsì ti Ìjẹ̀bú igbó
Àti Kábíèsí Òbìrí ní Ayépé
Lorúkọ gbogbo Ọba ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Kábíèsí Ọba Onírù Abdulwazir
Gbọ́láhàn ọmọ Lawal ‘m’amúbíẹyá ọkọ olorì Mariam Baby
Àti Kábíèsí Eléguṣì Ọba Adémọ́lá
Ọkọ olorì Arámidé Sekinatu mo dúpẹ́ dúpẹ́
Fọláṣadé Àdùnní Risikiyatu
Ọmọ ti Araga Ṣóṣànyà nílùú Ìjẹ̀bú Òde
Ayọ̀ Ọ̀túnba Gbóyèga ọmọ Ṣọ́yè Àdùnní mo mọ̀ ọ́ lóore
Àbúrò Àyìndé mi Wasiu mother Azeezz mi
O kú àdúrótì lójoojúmọ́ àbúrò Bukky Bùkọ́lá
Ọ̀rẹ́ Mopélọ́lá Àdùnní Mufutiatu aya Savagee
Ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Yétúndé Àdùnní Kudiratu ọ̀rẹ́ mi
Aya Honourable Oyinlọmọ Yàrámọlé
Ọmọ onífẹ̀ abùrẹ́ arówórorí má mà r’ọ́rùn fi gbe
Ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ Yétúndé
Gbogbo Ọ̀túnba l’ákilẹ̀ Ìjẹ̀bú mo dúpẹ́ dúpẹ́ mo t’ọ́pẹ́ dá
Ẹ kú àdúrótì arábámbí
Mo wá ń bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun Ọba o
Ṣe ikú ni ìsinmi fún ìyá mi Alimo Sadia ọmọ Moria Alége
Mother Àdùnní Serifatu Àdùnní adé mo ki yín
Ẹ ti di màmá fún gbogbo wa
Ọlọ́hun á fún ẹ ṣe Àdùnní o
Mother Àyìndé mi Wasiu Árábámbí
Mother Moriamo mo kí ẹ ọ̀run re
Mother Mufutau mi Àlàdé Babátúndé
Mother Ramotalahi Oríyọmí ìfánú ìyá
Ramota o kú àdúrótì ìyá mi Alimotu Ṣadia
Àti ọmọ àti ọ̀pọ̀ ọ̀pọ̀ ọmọ ọmọ
Ẹ kú ará fẹ́rakù gbogbo yín ni mo kí
Láti Ìjẹ̀bú dé ìlú Ìlúpéjú ní Èkìtì
Alága Rabiatu mi Andawi ìyá mi ẹ kú ará fẹ́ra kù mo ki yín
Mother Bísí Bísí
Andawi ilé d’ọwọ́ ẹ ẹ̀ ri bí
Alhaja Basira Ògbúnbóyèjọ o
Ọmọ Alhaji Àgbà mo ki yín ẹ kú ará fẹ́ra kù
Basira mé le gbàgbé yín
Mo kí Shidi Ìkòyí o ṣé
Abdulrashidi ọmọ Subedatu ẹ kú ará fẹ́ra kù
Ìyá mi Alimotu Sadia Àbíkẹ́ relé
Lorúkọ gbogbo ẹbí ní Ìlúpéjú
Mo kí General Samuel bàbá mi Dáramọ́lá
Mo ki yín ẹ kú ará fẹ́ra kù
Mo kí Israel ọmọ Dáramọ́lá àti gbogbo ẹbí Akérédolú
Àwọn ọmọ Bàbá Sójà mo ki yín sílé
Mo kí wọn nílé bàbá mi Fìdípọ̀tẹ̀ ní Ìjẹ̀bú Òde o ní Ìjẹ̀bú Òde
Ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́
Gbogbo ilé Ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin l’ákilẹ̀ Ìjẹ̀bú
Mo dúpẹ́ mo t’ọ́pẹ́ dá àdúrótì olórí ọmọ Ọba
Gbogbo àwọn Alihulamohu pátá pátá
Mo ki yín ẹ kú àdúrótì
(Islamic recitation )
Àyìndé mé le gbàgbé yín
Mo kí gbogbo ẹgbẹ́ TAMPAN ANTP ISMAN
Ẹgbẹ́ FUMAN AJUM NURTW pẹ̀lú ROAD
Ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́
Àyìndé Musiliu Ayédáadé àti Sapha SEGO mo dúpẹ́ dúpẹ́
Ọmọ Eté Eféle Akibu mo dúpẹ́ dúpẹ́
Kábíèsí JAFO Authority
Obíbà ẹkùn mo kí ẹ afẹjayanẹja
Ọ̀kanlọmọ Aríremákọ̀ ọlá bàbá Yusufu
Kábíèsí Ifákáyọ̀dé mo dúpẹ́ dúpẹ́
Aláyélúwà ìlú Ọ̀gọ̀m̀bọ̀ mé le gbàgbé yín
Ìyá mi Àbíkẹ́ relé
Alimo Sadia Àbíkẹ́ relé
Bólúadé ọmọ Akérédolú lọ o
Àbíkẹ́ relé
Ìyá mi sùn-un re bo bá ti d’ọ́run
Abiamọ tó ṣe ohun dáadáa sílẹ̀
Àbíkẹ́ mo kí ẹ Bólúadé
Ìlúpéjú Development Association ẹ kú àdúrótì
President gbogbo Ìlúpéjú IDA mé le gbàgbé yín
Gbogbo ẹgbẹ́ ọlọ́jà ní owólòwò market l’ágàràú area
Mo dúpẹ́ dúpẹ́ ẹ ṣeun mi
Láti orí ìyá ọjà Alhaja Idia Alli ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Nítorí ìyá gbogbo ọjà Àbíkẹ́ adé Alimotu Sadia Bólúwadé
Barrister Ṣọlá ọmọ Abídákun o
Barrister Báyọ̀ Adékọ̀yà àti Àjídé Moshoodi
Fákóredé mi Bashiru ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Ọmọ Alégẹńbì ìyá mi Àbíkẹ́ relé
Bólúwadé ọmọ Alégẹńbì ìyá mi Àbíkẹ́ relé
Lamex Àkànní Ọláńrewájú lórúkọ Royal Pioneer
Ṣèyí Vodi Jésù gbogbo ránṣọ ránṣọ láti ìlú Abuja
Bashiru Kuti mi BKK anọbi gbogbo ránṣọ ránṣọ
Muddy Exclusive Fashion ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́
Ah Àbíkẹ́ relé
Èrò tí ń r’òjéje ẹ bá mi kí màmá mi
(Ẹ kí màmá mi fún mi o)
Èrò tí ń r’òjéje ẹ bá mi kí màmá mi
(Ẹ kí màmá mi fún mi o)
Written by: Babatope Joseph Temidayo, Olasunkanmi Ayinde Marshal