Music Video

Featured In

Credits

PERFORMING ARTISTS
K1 De Ultimate
K1 De Ultimate
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Composer

Lyrics

[Verse 1]
Awa tun de bi a ṣe n de
Doctor Ọmọgbọlahan, ma fiyin f'Ọlọhun Ọba
Ọba to jẹ pe ma a bẹ ọwọ ẹ lo wa
Aitun ni bẹ mọ Wasiu n bẹ lọwọ Ọlọhun Ọba
Ọba aiku to lana to leni, Ayinde Wasiu to lọjọ gbogbo
Alabinu a maa sa si
Tori pe ṣe temi Ọmọgbọlahan mi aṣẹ Ọlọhun Ọba ni
Ma forin ma fiyin f' Eledumare ma fogo f'Ọlọhun Ọba
[Verse 2]
Ọlọhun ayọ, Ọlọhun ayọ mo woju rẹ o
Wa bawa ṣe Baba o, kọrọ wa ko dayọ
Tete ba wa ṣe, koju ma ṣe ti mi o, ko ba mi ṣe
Ẹda lo n sare
Ṣebi final decision n bẹ lọwọ Ọlọhun
Mo ti fọrọ mi l'Ọlọhun lọwọ
Jọwọ ma ṣe jẹ kọta beere wi pe nibo l'Ọlọhun temi wa
Ilahi Eledumare mi maa ṣọ mi lọjọ gbogbo
[Verse 3]
Mo n wa jijẹ mimu lọ loni o
Ipadabọ mi Eledumare ma jẹ n kawọko lofifo
Tori ohun a ma jẹ la n wa
Ka ma ṣe pade ohun ti o jẹ wa
Iwọ lo ni ka beere pe iwọ Eledumare wa ba wa faṣe si
[Verse 4]
Ajagunṣẹgun, Ajagunṣẹgun
Mo woju ẹ o
Wa ba mi ṣe temi Baba
Ọrọ wa ko dayọ
Tete ba mi ṣe
Koju ma ṣe ti mi o, ko ba mi ṣe
Ibi ẹnikan gbe n sare owo
Lọkan gbe n sunkun ọmọ o
Bẹẹ, awọn kan n sunkun alaafia
Emi dẹ gba p'Ọlọhun Ọba gbọ Wasiu o ti ba wa faṣẹ si
[Verse 5]
Ka ṣe werewere ka ba wọn lọ, ka ṣe warawara ka ba wọn lọ
Ka ṣe werewere ka ba wọn lọ, ka ṣe warawara ka ba wọn lọ
Ani ka ṣe werewere ka ba wọn lọ, ka ṣe warawara ka ba wọn lọ
Ka ṣe werewere ka ba wọn lọ, ka ṣe warawara ka ba wọn lọ
[Chorus]
O wa di lailo (Lailo)
O wa di lailo (Lailo)
Alọ mi alọ o (Lailo)
Alọ mi alọ o (Lailo)
A ranmọ lakara o (Lailo)
Akara ṣaaju ọmọ dele (Lailo)
O dele o tun parọ (Lailo)
Ọrọ ko sotitọ (Lailo)
Wọn lohun lo fira han (Lailo)
Ẹyin ọmọde (Lailo)
Ọmọde eni o (Lailo)
Otitọ lo yẹ ka ṣe (Lailo)
Ka ṣa maa ṣe daadaa (Lailo)
Written by: Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
instagramSharePathic_arrow_out